WON TI GBE KALU KURO NI NIJIRIA LO SI GERMANY O - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Friday, November 2, 2018

WON TI GBE KALU KURO NI NIJIRIA LO SI GERMANY O

Latari bi ajo EFCC se fi oruko gomina teleri nipinle Abia Dokita Orji Uzor Kalu mo awon àádọta ti won ko lanfaani lati jade kuro lorileede yi, sibe won ti gbe Kalu kuro ni Naijiria bayii.


AWÍKONKO gbo pe digba-digba ni won gbe Kalu lo sí orílẹ̀-èdè Germany lojo Monde ọsẹ yi latari àìsàn to ṣeé ṣe kó la emi lo, eyi ti won lo n ba a já lati bi ojo pipe seyin.

Iṣẹ abe la gbo pe won loo se fún Orji Kalu, ta a sí gbo pe o ti n gbádùn diedie bayii.

Ogbeni Kunle Oyewunmi to je agbenuso lori oro iroyin e, lo fi oro naa sita fawon oniroyin laaro oni.

PÍN-IN KÁÀKIRI