KO SENI TO LE SO PE KI ADEKUNLE AKINLADE MA DI GOMINA LODUN 2019 - AMOSUN - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Monday, December 3, 2018

KO SENI TO LE SO PE KI ADEKUNLE AKINLADE MA DI GOMINA LODUN 2019 - AMOSUN


Gomina Ibikunle Amosun tipinle Ogun ti so pe gbogbo nnkan to ba gba loun máa fún ùn lati ríi dájú pé adije oun sipo gomina nipinle naa lodun 2019 wole, ti yoo si dojú ti awọn ota alatako patapata.

Gomina Amosun lo soro yi nibi ìpàdé tó ṣe pẹlu awọn ọmọ ẹgbẹ naa ninu gbagede Presidential Lodge to wa niluu Abeokuta losan oni, Monde.

Nibe lo ti so pe ko seni to le ba oun sọ ọ wipe koun ma sagbateru ẹni tóun fa kale lati gba ipò náà lowo oun, nitori pe eni kan soso to le tẹsiwaju iseju toun to se l'ase pati.

O ni bo tile je pe gbogbo ona láwọn to mu madaru wo ẹgbẹ oṣelu won ti n dogbon bẹ oun labele lati sise fún wọn, sibe se ni won tun n ba oun loruko je kaakiri n'ita gbangba toun sí mo pe ijakule ni won yoo ba pade.

"Awon alawada ti wa a ba mi lopo igba lati bẹ mi pe ki n dariji oun latari magamago ti won se lasiko idibo pamari to koja, bi won se n bẹ mi naa ni won tun n takò mí n'ita gbangba, ti won n bami loruko je kaakiri.

"Se iru awon ta a fe e dibo fun naa ni yii. Ko seni to le so pe oun feran Aare Muhammadu Buhari, ti yóò tún máa ṣe awuruju, nitori gbogbo wa la mo pe eeyan ti kii se ojusaaju ni Aare wa je."

Bakan naa ni Gomina Amosun tun je kó di mi mo pe oun ti gbaradi lati ba awon alatako ẹgbẹ oṣelu naa já dé gongo, iyen bi won ba wa a koju oun lasiko ipolongo.

Siwaju sii lo ni bo tile je pe awọn ti won fowo ola gba loju ninu ẹgbẹ, iyen awon adije sipo omo ile igbimo asofin ipinle Ogun ti wa a ba oun pe awon fe é fegbe sile lo sí ẹgbẹ min in, toun sí bẹ won pe won ko gbodo lo, sugbon nigba toun ri í pe inu won ko dun, ti won sì fẹ é fi ipo tawon omo ipinle naa fe e fún wọn sofo danu, lo je koun gbà fún wọn láti lò.

O loun ti muu da wọn loju pe oun yoo sagbateru won, niwon igba to ba ti je pe Onarebu Akinlade, iyen omo oun ni won fe e lo gege bi adije.

Bẹẹ lo tun fi kun ùn ọrọ e pe b'oun bá n jade du ipo nipinle Ogun, paapaa ipo Seneto nigba milionu, oun loun yoo bori, toun yóò sì foju eni to ba fẹ e ba oun figagbaga gbole.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI