Ẹ GBỌ́ KÍ LÈ RÍ SÍ I ?: ÀWỌN ONÍMỌ̀ NÍ ÀWỌN OBÌNRIN TÍ Ó GA TÍ WỌN Ò SÌ SANRA NÍ ÀǸFÀNÍ SÍ Ẹ̀MÍ GÍGÙN JU ÀWỌN ÌYÓKÙ LỌ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Thursday, January 24, 2019

Ẹ GBỌ́ KÍ LÈ RÍ SÍ I ?: ÀWỌN ONÍMỌ̀ NÍ ÀWỌN OBÌNRIN TÍ Ó GA TÍ WỌN Ò SÌ SANRA NÍ ÀǸFÀNÍ SÍ Ẹ̀MÍ GÍGÙN JU ÀWỌN ÌYÓKÙ LỌ



Ìwádìí tí àwọn onímọ̀ kan ṣe lórí bí ọkùnrin àti obìnrin ṣe ń pẹ́ láyé sí ti fidìí rẹ̀ múlẹ̀ pé àwọn ọpẹ́lẹ́ngẹ́ obìnrin tí wọ́n ga dáadáa ní àǹfàní láti pẹ́ dáadáa láyé kí wọ́n sì lò tó àádọ́rùn-ún ọdún lókè eepẹ̀.

Ìwádìí náà, èyí tí àjọ ìlera kan gbé sórí ẹ̀rọ ayélujára, fidìí rẹ̀ múlẹ̀ pé lílọ bíbọ̀ ẹ̀dá jẹ́ igi lẹ́yìn ọgbà fún bí ènìyàn ṣe lè pẹ́ láyé sí nítorí náà ni àwọn ọkùnrin tí wọn kò jókòó sójú kan fi máa ń pẹ́ díẹ̀ láyé ju àwọn ìyókù lọ.

Wọ́n ní àwọn obìnrin tótó ẹ́rìndínláàdọ́talélèdẹ́gbẹ̀rún (944) nínú àwọn tí wọ́n lò fún ìwádìí náà ni ó pé àádọ́rùn-ún ọdún.

Wọ́n ní àwọn obìnrin náà ni ga nìwọ̀n tó yẹ tí wọn kò sì sanra rara èyí tí kò rí bẹ́ẹ̀ fún àwọn ọkùnrin.

Gẹ́gẹ́ bí ìwádìí ṣe rí báyìí, kí lojú tí ẹ fi rí i? Ṣe ẹ gbà pé bẹ́ẹ̀ lọ̀rọ̀ máa ń rí? Ẹ bá wa dá sí i lórí Whatsapp wa: 07012342712. 


No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI