Ẹ WO OGBOLOGBO ỌMỌDUN MEJILA TO N JALE - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Saturday, January 26, 2019

Ẹ WO OGBOLOGBO ỌMỌDUN MEJILA TO N JALE

Folukẹ Aduragbemi 

Kani aṣiri ọmọdebinrin, ẹni ọdun mejila ti wọn ni ko niṣẹ meji ju ko maa jale lọ, ṣee ṣe ko tubọ tẹramọ iṣẹ naa, ko si tun lawọn ọmọṣẹ rẹpẹtẹ labẹ, ti yoo maa ṣiṣẹ fun un.

O ti pẹ ti wọn ni ọmọdebinrin naa ta a ko tii mọ orukẹ dasiko ta a kọ iroyin yi tan ti maa n dawọn araadugbo ẹ, iyẹn lagbegbe Amaeke Utu, ijọba ibilẹ Arochukwu, ipinlẹ Abia laamu, ti wọn loo si maa jẹ ko ye wọn pe ko si nnkan ti ọkunrin le ṣe toun ko le ṣe ju bẹẹ lọ.

Nigba taṣiri ẹ maa tu, oru mọju ọjọ aarọ yii la gbọ pe o lọọ ja ṣoobu kan ti wọn ti n taja oriṣiriṣi, to si ko wọn lawọn ọja bii miliki, indomi atawọn ounjẹ loriṣiriṣi.

 

Baṣiri ẹ ṣe tuu, nibi to ti n jẹwọ awọn iwa buruku to ti hu, o ni oun loun lọọ ja ṣoọbu nla kan lagbegbe naa lọjọ Wẹside to kọja yi.

Lẹsẹkẹsẹ ni wọn ti lọọ fa a le awọn ọlọpaa lọwọ gẹgẹ ba a ṣe gbọ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI