Ọla Eyitayọ, Ọyọ
Ajọ eleto idibo orileede Naijiria INEC ti kede sita pe awọn ti fi ọjọ mẹta gbako kun gbedeke ọjọ ti awọn oludibo yoo lanfaani lati gba kaadi idibo alalopẹ wọn.
Ọjọ Fraide onii, tii ṣe ọjọ kẹjọ oṣu keji ni wọn ti ṣaaju da
lọjọ gbedeke gbigba kaadi yii, ṣugbọn ni bayii, alaga ajọ naa ọjọgbọn Mahmood Yakubu ni
awọn oludibo le gba kaadi naa titi di ọjọ Mọnde tii ṣe ọjọ kọkanla oṣu keji 2019.
Ọjọgbọn Yakubu lọ kede isun-siwaju yi ninu ipade kan
to ṣe pẹlu awọn adari eto idibo lawọn ipinlẹ lọjọ ẹti.
INEC ni ọjọ Abamẹta ati ọjọ Aiku yoo kun ọjọ ti awọn
eeyan yoo fi gba kaadi naa bẹrẹ laago mẹsan aarọ di ago mẹfa irọlẹ.
Kaadi idibo ọlọjọ pipẹ, PVC ni aami idanimọ ti awọn
oludibo yoo lo lati fi kopa ninu idibo gbogboogbo 2019 to wọle tan.
Eyi kii ṣe igba akọkọ ti ajọ INEC yoo sun gbedeke
ọjọ gigba kaadi idibo sṣiwaju-ọjọ kọkanlelogun oṣu kinni ọdun 2019 ni wọn ṣaaju da,
ṣugbọn wọn sun siwaju lẹyin ti wọn ri i pe pupọ ara ilu ni ko ri kaadi naa gba.
Kaadi idibo yi ni wọn fi aworan ati orukọ to fi mọ
awọn iroyin miran to ṣe koko nipa oludibo si. Ẹni ti ko ba ni kaadi yi ko ni le
dibo bẹẹ si ni eeyan kan ko le fi kaadi elomiran dibo.
No comments:
Post a Comment