ABIỌDUN LU MAGUN LARA IYA ARUGBO L'ABẸOKUTA - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Thursday, February 21, 2019

ABIỌDUN LU MAGUN LARA IYA ARUGBO L'ABẸOKUTA

Bọsun Ọlaniyi, Abeokuta 

“Ẹ pami sile, ẹ ma pami sita” lọrọ ẹbẹ to n tẹnu iyaale ile ẹni ọdun marundinlaadọta kan, Aderokẹ Ayinde, ẹni ti wọn sọ pe aale ku sori ẹ ninu yara lasiko ti wọn ba ara wọn laṣepọ lọwọ.

AWIKONKO gbọ pe agboole Asalu ladugbo Ijẹmọ niluu Abẹokuta niṣẹlẹ naa ti waye lọjọ Wẹside ana, nigba ti wọn sọ pe aale Aderonkẹ, Aṣimiu Abiọdun lu Magun lara ẹ.

Ohun ta a gbọ ni pe kii ṣe akọkọ re e, ti Abiọdun ati Aderonkẹ ti n yan ara wọn ni ale, ti ko si sẹni ti ko mọ ladugbo Ijẹmọ ti Aderonkẹ n gbe, paapaa bi wọn ṣe sọ pe ko si ọsẹ kan ki Abiọdun ma wa a sun lọdọ Aderonkẹ, ti wọn a si gbadun ara wọn daadaa ki ilẹ too mọ.

Bo tilẹ jẹ pe titi di asiko ta a kọ iroyin yi tan, ko tii sẹni to le sọ pato ẹni to le Aderonkẹ ti wọn sọ pe abẹ ẹ lo fi n jẹun ni magun, ṣugbọn ti obinrin naa sọ pe aisan to de si laarin oru lo ṣeku pa a.

Nigba ti akara maa pada tu sepo, taṣiri yoo tu, alẹ ijẹta tii ṣe Tuside la gbọ pe Abiọdun tun lọ sile Aderonkẹ gẹgẹ bo ṣe maa n lọ, ti wọn si jẹun, ti wọn tun ṣere gẹgẹ bii ise wọn.

Nigba to di aarin oru, tasiko to lati gbadun ara wọn, wọn ni nibi ti wọn ti n ṣe kinni in naa lọwọ ni Abiọdun ti bẹrẹ sii pariwo, ṣugbọn ti ko sẹni to gbọ ninu awọn araale, nitori pe gbogbo wọn ti sun lọ.

Wọn ni ṣe ni Abiọdun gbokiti titi to fi ku.

Kaṣiri ma baa tu, wọn Aderonkẹ ko ro o pe meji, to fi palẹmọ oku Abiọdun lati lọọ sọọnu sinu igbo kan to wa nitosi ile ti Aderonkẹ n gbe, lai mọ pe awọn ọlọdẹ n to wa nitosi ri i.

Lẹsẹkẹsẹ lọwọ si ti tẹ ẹ, aarọ ọjọ keji ni wọn lọọ fa a le awọn ọlọpaa Oke-Itoku lọwọ, ta a si gbọ pe awọn ọlọpaa ni wọn pada gbe oku Abiọdun lọ si mọṣuari lati ṣe ayẹwo ti wọn maa n ṣe lara oku ki wọn le mọ iru iku to pa a.

Alukoro ọlọpaa, Abimbọla Oyeyẹmi fidi iṣẹlẹ naa mulẹ, o si sọ pe iwadii ti bẹrẹ lori ẹ ni pẹrẹu, ati pe awọn ti ranṣẹ sawọn mọlẹbi oku naa lati wa sọ tẹnu wọn.

Titi di asiko ta a kọ iroyin yi tan, gbogbo awọn araale naa la gbọ pe wọn ti na papa bora, ki ọwọ ọlọpaa ma baa tẹ wọn lati jiya ti wọn ko mọwọ m'ẹsẹ. Ṣugbọn ṣa, ohun tawọn eeyan n sọ ni pe nnkan ti Abiọdun mọn ọn jẹ lo ṣeku pa, bẹẹ ni wọn n sọ pe ohun ti oju Aderonkẹ n wa lo ri nitori pe ọpọ igba ni wọn ti kilọ fun un pe ko jawọ ninu iwa agbere ti ko gbọ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI