IDIBO TI WỌN SUN SIWAJU KO ṢẸYIN ASỌTẸLẸ TB JOSHUA - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Saturday, February 16, 2019

IDIBO TI WỌN SUN SIWAJU KO ṢẸYIN ASỌTẸLẸ TB JOSHUA

Folukẹ Aduragbemi, Ọṣun

Iyalẹnu lọrọ naa ṣi n jẹ fawọn eeyan nigba ti wọn gbọ wi pe asọtẹlẹ ọkan lara awọn gbajumọ Wolii lorileede Naijiria, iyẹn Wolii TB Joshua ni nnkan bi ọjọ meloo kan sẹyin wi pe eto idibo ko ni i waye loni-in Satide, ọjọ kẹrindinlogun oṣu yii gẹgẹ bi Ọlọrun ṣe fi han oun.

Ni nnkan bi ọjọ meloo kan sẹyin ni  gbajugbaja Wolii agbaye naa, TB Joshua sọ wi pe, ti ajọ INEC ko ba mura daadaa, o ṣee ṣe ki eto idibo ma waye loni-in gege bi ajọ ọhun ṣe la a kalẹ.

Lasiko ti Wolii ijọ Synagogue of All Nations, eyi to wa ni lagbegbe Ikotun niluu Ekoo n ṣe waasu fun awọn ọmọ ijọ ẹ lo fi wọn lọkan balẹ wi pe wahala kan bayii ko ni i ṣẹlẹ lori idibo ni Naijiria, ṣugbọn bi Ọlọrun ṣe fi han oun, ibo ko ni i waye lọjọ ti ajọ INEC kede e, ati pe ohun ti yoo fa a ko ni i se lẹyin awọn kudiẹ-kudiẹ kọọkan to maa waye.

Ninu ọrọ ẹ lọjọ naa lo ti sọ pe “Ibo ta a fe di ni Naijiria lọjọ kẹrindinlogun yẹn, o ṣee ṣe ki o ma waye latari awọn kudiẹ-kudiẹ kọọkan to maa waye, ṣugbọn mo nigbagbọ wi pe agbara Ọlọrun yoo ka a.”

Bo ṣe sọrọ ọhun niyẹn o, nigba to si ku dẹdẹ loootọ ki eto ibo waye loni-in, nni ajọ naa atawọn ti ọrọ kan ba wọle ijiroro lati ọwọ irọlẹ ana Fraide ọjọ kẹẹdogun, nigba ti wọn yoo si pari ipade, nibẹ gan-an ni wọn ti sọ pe ibo ko ni i le waye mọ loni-in, o di Satide to n bọ, nitori awọn gbọdọ mura silẹ fun un daadaa, ki ibo naa le kẹsẹjari.

Ṣa o, Ọgbẹni Yakubu Muhammed, ẹni ti i ṣe olori ajọ naa ti sọ pe orinkinniwin alaye lori ohun to mu awọn taari ibo ọhun siwaju lawọn yoo pe ipade awọn oniroyin lee lori ni deede aago meji ọsan oni.

- Magasinni Alore

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI