KO SI NNKAN TO BURU NINU YAHOO-YAHOO TAWỌN ỌDỌ N ṢE - ADIJE SIPO GOMINA, OGUNBANJỌ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Friday, February 8, 2019

KO SI NNKAN TO BURU NINU YAHOO-YAHOO TAWỌN ỌDỌ N ṢE - ADIJE SIPO GOMINA, OGUNBANJỌ

Bọsun Ọlaniyi, Abeokuta

Oludije sipo gomina ipinlẹ Ogun labẹ ẹgbẹ oṣelu Alliance for New Nigeria, Ọgbẹni Ademọla Ogunbanjọ ti sọ ọ di mimọ pe ko si nnkan to buru ninu iṣẹ gbajuẹ ori ẹrọ ayelujara tawọn ọdọ orileede yi n ṣe, paapaa lasiko oṣelu to n lọ lọwọ lorileede yi.

Ọgbẹni Ademọla Ogunbanjọ lo sọrọ naa nibi ipade itagbangba pẹlu awọn adije sipo gomina nipinlẹ naa, eyi ti ileeṣẹ BBC Yoruba gbe kalẹ niluu Abẹokuta, lonii Fraide ninu gbọngan ile ikawe ti Oluṣẹgun Ọbasanjọ.

Ọgunbajọ nigba to n dahun ibeere pe ki lo fẹẹ ṣe si ọrọ awọn ọdọ to n lu jibiti ori ẹrọ ayelujara, iyẹn Yahoo-Yahoo, ati pe ọna wo lo fẹẹ gba lati dẹkun ẹ, o sọ pe ko si nnkan to buru nibẹ nitori pe airikan-ṣekan to n dawọn ọdọ laamu lo sun wọn de be.

Ninu ọrọ ẹ, "Mi o ri nnkan to buru nibẹ nitori pe iwa tawọn olori i wa n hu lo sun wọn de bẹ, nigba tawọn naa kii ṣe ọlẹ lo jẹ ki wọn wa ọna ti wọn yoo fi maa ri ọwọ mu lọ sẹnu. Kani awọn ijọba, iyẹn awọn olori i wa ti pese ọna bi awọn naa yoo ṣe maa ri ounjẹ jẹ, ki ni wọn fẹ ki wọn ṣe?.

"Awọn ọdọ kii ṣe ọlẹ, bi wọn ko ba ṣe Yahoo-Yahoo, ki lẹ fẹ ki wọn maa ṣe, abi ẹyin ri iṣẹ nita ni. Bi ọna min in ba wa lati maa ri owo, ẹ maa rii pe ko ni sẹni to maa ronu nipa jibiti ori ẹrọ ayelujara. Bi mo ba de bẹ, bi ẹ ba ran mi niṣẹ gẹgẹ bi ọmọde, mo ni idaniloju pe ẹ ko nii gburo nnkan to jọ bẹẹ mọ."

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI