AKINLADE JU BỌMBU ỌRỌ SI GOMINA AMOSUN NITA GBANGBA, AFAIMỌ KI WAHALA MA ṢẸLẸ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Friday, February 8, 2019

AKINLADE JU BỌMBU ỌRỌ SI GOMINA AMOSUN NITA GBANGBA, AFAIMỌ KI WAHALA MA ṢẸLẸ

Bọsun Ọlaniyi, Abeokuta


Pẹlu ọrọ ti adije sipo gomina labẹ ẹgbẹ oṣelu APM, Ọnarebu Adekunle Akinlade sọ nipa ipo tipinlẹ Ogun wa lonii, afaimọ ko ma jẹ pe Gomina Amosun yoo pada lẹyin ọkunrin naa nitori pe kayeefi lọwọ naa ṣi n jẹ leti gbogbo awọn araalu, paapaa awọn to wa nibi ipade itagbangba fawọn gomina, eyi ti ileese BBC Yoruba ṣagbekalẹ ẹ.

Ọnarebu Adekunle Akinlade tawọn eeyan tun n pe ni Triple A, ẹni ti gomina Amosun fa kalẹ lati tako adije ti ẹgbẹ oṣelu APC fa kalẹ, iyẹn Ọmọba Dapọ Abiọdun lo bu ẹnu atẹ lu ijọba gomina Amosun, to si ni inu awọn araalu gan an ko dun si ipo tipinlẹ naa wa.

Ninu ọrọ ẹ, Akinlade ni, “Mo fe ko da wa loju, mo si ti n so kaakiri gbogbo ibi ti mo ti de pe, ni gbogbo awa adije patapata ta a wa nibi yi, emi ni kan ni mo ti lo kaakiri woodu igba ati mokanla (211) lati ojo keji osu kinni odun yi titi dasiko yi.

“Mo fi n ye won, mo ti ri aini, mo ri ipo ainireti tawon eeyan wa wa, afi ti eeyan ba je ika nikan leeyan maa so pe nibi ti mo ba de yi pe maa se sibi bayii, mi o ni se sibi kan.”

Bi Akinlade ṣe sọrọ naa tan, lawọn to eeyan to gbọ nnkan ti Akinlade sọ yi ti bẹrẹ sii bu ẹnu atẹ lu ọrọ ti ọkunrin naa sọ, ti wọn si n sọ pe alaimoore ni, nitori pe ṣe lo dabi ẹni to wa a yẹyẹ ọga ẹ nita gbangba.

Ohun tawọn min in tun sọ ni pe o ṣee ṣe ko jẹ pe asasi awọn ẹgbẹ alatako to mu ọkunrin naa to fi sọ iru ọrọ bẹẹ jade sita, paapaa nigba ti adije sipo gomina labẹ egbe oṣelu African Democratic Congress, ADC, Ọmọba Gboyega Isiaka naa dupẹ lọwọ ẹ pe inu oun dun nitori pe o sọ otitọ ọrọ, ko si fi bo rara. 

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI