Aarẹ orileede Naijiria, Ọgagun Muhammmadu Buhari ti pariwo sita fawọn oludibo pe ki wọn jade sita lọpọ yanturu lati dibo apapọ orileede yii ti yoo waye lọjọ Satide Abamẹta tii ṣe ọla.
Bẹẹ lo fọkan awọn araalu balẹ
pe idibo naa yoo lọ nirọwọ-irọsẹ, nitori naa ki wọn ma ṣe jokoo sile maa ṣere
tabi wo tẹlifiaṣan, bi ko ṣe pe ki wọn lọọ ja fun ẹtọ wọn lati yan ẹni to wu
wọn sipo ninu awọn oludije.
Aarẹ sọrọ yii nigba to ba awọn
ọmọ Naijiria sọrọ lori ẹro amohun-maworan ti ijọba apapọ, NTA ati ile iṣẹ Radio
Naijiria laarọ oni ṣaaju idibo ọjọ Abamẹta Satide.
Aarẹ Buhari ni awọn oṣiṣẹ eleto
aabo ti wa ni digbi lati daabo bo gbogbo eeyan nibi ti wọn ba ti n dibo wọn.
O ni ko si iyi to ju ki awọn
eeyan dibo fun olori ti wọn fẹ ko maa dari wọn lọ gẹgẹ bi ọmọ orileede tootọ.
Aarẹ Buhari fikun ọrọ ẹ pe ajọ
eleto idibo, iyẹn INEC ti ṣetan lati ṣagbatẹru idibo ti yoo lọ ni irọwọ-irọsẹ
lọjọ Abamẹta.
Aarẹ tun fi da awọn onwoye lati
ilẹ okeere loju pe ko si ewu rara fun wọn, o ni aabo to peye yoo wa fun wọn
lọjọ idibo.
Bẹ o ba gbagbe, Aarẹ Buhari
bawọn ọmọ Naijiria sọrọ lọsẹ to kọja ki ajọ eleto idibo INEC to sun ibo to yẹ
ko waye lọjọ kẹrindinlogun, oṣu keji siwaju.
No comments:
Post a Comment