EYI NI BI BUKỌLA SARAKI ṢE FIDI RẸMI NI KWARA SỌWỌ OLORIẸGBẸ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Monday, February 25, 2019

EYI NI BI BUKỌLA SARAKI ṢE FIDI RẸMI NI KWARA SỌWỌ OLORIẸGBẸ

Folukẹ Aduragbemi, Ọṣun 

Bo tilẹ jẹ inu idunnu ati ayọ ni gbogbo ọmọ ipinlẹ Kwara wa bayii, sibẹ ohun ta a gbọ ni pe ṣe lawọn ọmọ ipinlẹ naa diju mọri nigba ti wọn n dibo apapọ orileede yi lọjọ Abamẹta Satide to kọja lọ.

Nnkan to ti ẹ jẹ kayeefi fawọn eeyan, paapaa awọn ti wọn ko si nipinlẹ Kwara, ṣugbọn ti wọn n tẹlẹ bi nnkan ṣe n lọ si nibẹ ni pe ariwo ole ti wọn n pa mọ Abẹnugọn ile igbimọ aṣofin agba orileede yi, Sẹnetọ Bukọla Saraki nibi to ti lọọ dibo lai bẹru awọn ẹsọ to tẹle e.

Odu ni akọṣẹmọṣe oniṣegun oyinbo Ibrahim Oloriẹgbẹ, ti o si ti n gbiyanju lati di aṣoju agba lọjọ to ti pẹ nipinlẹ Kwara.

Ibrahim ati Saraki gẹgẹ ba a ṣe gbọ, awọn mejeeji ti kọkọ koju ara wọn lọdun 2011 nigba ti Saraki bẹrẹ irin ajo rẹ gẹgẹ bi aṣofin agba. Aburo Bukọla Saraki, Sẹnẹto Gbemi Saraki lo ṣẹṣẹ pari saa rẹ gẹgẹ bi Senẹtọ ti awọn mejeeji sijọ du ipo naa.

Lọdun naa lọhun, abẹ asia ẹgbẹ oṣelu ACN ni Oloriẹgbẹ ti dupo ko too di pe Sẹnetọ Bukọla Saraki toun wa ninu ẹgbẹ oṣelu PDP nigba naa fẹyin rẹ gbolẹ.

Laarin ọdun 1999 si 2003, Ibrahim Oloriegbe jẹ olori awọn ọmọ ẹgbẹ to pọju lọ nile asofin ipinlẹ Kwara.

O tun joye alaga igbimọ ile to n mojuto ọrọ ilera ati eyi to n ri si ọrọ ijọba ibilẹ.

Lẹyin to pari nile asofin ko ti di ipo oṣelu kankan mu mọ lati igba naa.

Ohun to tun n jẹ kayeefi fawọn eeyan ni pe Dọkita Bukọla Saraki ko niile bawọn pada sile igbmọ aṣofin mọ, to si mu kawọn kan maa sọ pe igba ko lọ bi orere.

Ohun tawọn kan tun sọ bayii ni pe, afaimọ ko ma jẹ pe ọdun yi ni Saraki yoo gbẹyin aye rẹ sinu oṣelu orileede Naijiria ati nipinlẹ Kwara to ti lẹnu.

Fawọn ti ko ba mọ Dọkita Ibrahim Yahaya Oloriẹgbẹ lati ẹgbẹ oṣelu APC lo fidi Dọkita Bukọla Saraki janlẹ ninu eto idibo to waye lọjọ Satide ijẹta lati ṣoju aarin gbungbun ipinle Kwara, iyẹn Kwara Central.

Ibo ti Dọkita Oloriẹgbẹ fi la Dọkita Bukọla Saraki pọ jọjọ. Ẹgbẹrun lọna aadọrin din diẹ (68,994) ni ibo ti Dọkita Bukola Saraki ni, nigba ti  Oloriẹgbẹ ti wọn jọ fa a ni ibo to le ni ẹgbẹrun lọna ọgọfa (123,828).

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI