O MA ṢE O, NITORI APOTI IBO, WỌN YINBỌN PA ỌLỌPAA N’IPOKIA - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Monday, February 25, 2019

O MA ṢE O, NITORI APOTI IBO, WỌN YINBỌN PA ỌLỌPAA N’IPOKIA

Bọsun Ọlaniyi, Abeokuta 

Ṣe lọrọ di boolọ o yago ni alẹ ana, Sande ana nigba ti wọn lawọn janduku kan yinbọn pa ọkan lara awọn ọlọpaa ti wọn loo tẹle apoti ibo ti wọn di niluu Ipokia lọ si Ilaro, nibi ti wọn ti fẹẹ ko o ojọ.

Sunday Idọkọ ni wọn pe oruko ọlọpaa naa ti wọn pa danu.

Ohun ta a gbọ ni pe agbegbe Eredo nijọba ibilẹ Yewa South la gbọ pe awọn janduku naa ti pade wọn ni nnkan bi aago mẹjọ alẹ lasiko ti wọn ko gbogbo ibo ti wọn di fawọn aṣoju-ṣofin lẹkun Ipokia si Yewa South niluu Ipokia lọ si gbọngan Oronna to wa niluu Ilaro, nibi ti wọn ti fẹẹ ko o jọ.

Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun, Abimbọla Oyeyẹmi fidi ẹ mulẹ, o si jẹ ko di mimọ pe ko ni i pe ti ọwọ awọn yoo fi tẹ awọn ọdaran naa.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI