EYI NI BI GOMINA AMOSUN ṢE FI ẸYIN TITI OSENI GBOLẸ LẸYIN IDIBO - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Monday, February 25, 2019

EYI NI BI GOMINA AMOSUN ṢE FI ẸYIN TITI OSENI GBOLẸ LẸYIN IDIBO


Bọsun Ọlaniyi, Abeokuta
Bi ẹ ṣe n ka iroyin, bo tilẹ jẹ Gomina ipinlẹ Ogun, Ibikunle Amosun ko tii gbe ọrọ idupẹ ẹ jade, ṣugbọn tawọn eeyan ti gbe ọrọ sii lẹnu pe o ti ki awọn to dibo yan an sipo aṣofin agba niluu Abuja lẹkun Aarin gbungbun ipinlẹ Ogun, iyẹn Ogun Central, sibẹ inu idunnu ati ayọ ni lọkunrin naa wa bayii.


Fawọn to ba mọ bi nnkan ṣe n lọ daadaa nipinlẹ Ogun, woọn yoo mọ pe Ọnọrebu Titi Oseni-Gomez to ti figba kan ri jẹ abẹnugọn ile igbimọ aṣofin ipinlẹ Ogun lo jẹ ibẹru fun Gomina Amosun,nitori pe oun lọpọ awọn eeyan nigbagbọ pe yoo bori.

Ṣugbọn si iyalẹnu nigba ti esi ibo naa yoo jade sita, ko din ni aadọta ibo ni Gomina Amosun fi la obinrin naa, iyẹn Titi Oseni.

Bẹẹ, fawọn to ba n tẹle oṣelu ipinlẹ Ogun daadaa, aarin ọdun 2003 si ọdun 2007 ni Gomina Amosun ti fi wa gẹgẹ bi Sẹnetọ agbegbe yi, ko too tun jade dupo ipo Gomina, to si wọle lọdun 2011.

Bawọn kan ṣe n sọ pe owo ti Gomina Amosun na lati ri ipo naa gba lo funa, tawọn min in si n sọ pe iṣẹ rere to ṣe silẹ lo dahun fun un, to mu kawọn eeyan fi emi imoore han si.
 

Wọn yi ni bi akojọpọ ibo naa ṣe lọ si:
 

ABEOKUTA SOUTH LG
ADC - 10,592
ADP - 24
APC - 20,663
APM – 584
PDP - 8,264

ABEOKUTA NORTH LG
ADC - 7544,
ADP - 923.
APC- 18,385,
APM- 2,496,
PDP- 4, 118,

EWEKORO LG
ADC - 3,106
APC - 8,133,
APM - 1,325,
PDP, 3,671,

ODEDA LG
ADC - 3,726
APC -8, 217
APM - 1,365
PDP - 3,563

OBAFEMI OWODE LG
ADC - 4,242
ADP - 923
APC - 13,712
APM - 1,392
PDP - 6,691

IFO LG
ADC - 5,986
ADP - 980
APC - 19,000
APM - 2,974
PDP - 6,929

AKOJỌPỌ ESI IBO
ADC - 37,101
ADP - 6,510
APC - 88,110
APM - 10,039
PDP - 33, 276

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI