Gomina ipinlẹ Ekiti, Dọkita Kayọde Fayẹmi ti fọkan awọn araalu balẹ pe eto aabo to daju yoo wa lakoko ati lẹyin idibo to n bọ lọna yi.
Fayẹmi lo sọrọ yi niluu
Ado-Ekiti lasiko to n gba igbakeji ọga ọlọpaa nipa idanilẹkọ orileede yi,
Yakubu Jibril lalejo, o ni ko nii si wahala kankan lasiko ibo to n bọ yi,
nitori pe ẹgbẹ oṣelu APC ti ṣetan lati fọwọsowọpọ pẹlu gobgbo ileeṣẹ eleto aabo
patapata.
O ni irọwọ-irọsẹ ni eto ibo naa
yoo lọ nitori pe gbogbo eto lo ti pari.
Bakan naa nigba to n sọrọ lori
eto aabo ipinlẹ naa, o gboriyin fun Kọmiṣana ọlọpaa tuntun nipinlẹ naa, Asuquo
Amba fun iṣẹ takun-takun to n ṣe nipa aabo ẹmi ati dukia.
Nigba toun naa n sọrọ, Yakubu
Jibril gba awọn araalu lamọnran pe ki wọn fọwọsowọpọ pẹlu ajọ eleto idibo
atawọn agbofinro lasiko idibo.
No comments:
Post a Comment