Bọsun Ọlaniyi, Abeokuta
Ojiji ni yiyọ ti wọn yọ Kọmiṣana ọlọpaa ipinlẹ Ogun, Ahmed Iliyasu jẹ, pẹlu bi wọn loo ṣe gbabọdi lọjọ ti Aarẹ Muhammadu Buhari ṣe ipolongo idibo ipada sipo Aarẹ ẹlẹkeji rẹ wa siluu Abẹokuta lọjọ Mọnde to kọja yi.
Bo tilẹ jẹ pe gbogbo akitiyan
lati ba Ọgbẹni Abimbọla Oyeyẹmi sọrọ titi dasiko ta a kọ iroyin yi tan, lati le
fidi ọrọ naa mulẹ fun wa, ṣugbọn iroyin naa ti tan kaakiri igboro pe ibinu ni
wọn fi yọ iliyasu danu, pẹlu bi wọn loo ṣe gbabọdi lọjọ ipolongo Buhari naa.
Kii ṣe iroyin tuntun mọ pe wahala
nla lo ṣẹlẹ lọjọ Mọnde to kọja yi niluu Abẹokuta lasiko ipolongo APC, nibi
tawọn tọọgi ti sọ okuta, bata ati oriṣiriṣi nnkan lu alaga ẹgbẹ oṣelu APC,
Kọmureedi Adams Ọshiọmọlẹ, Aarẹ Muhammadu Buhari atawọn agbaagba ẹgbẹ oṣelu
APC, ko too di pe wọn fibinu kuro lọjọ naa.
Ohun ta a gbọ ni pe awọn ọmọ
ẹyin Dapọ Abiọdun ni wọn kọkọ da wahala naa silẹ nigba ti wọn ko gba awọn to n
ṣe ti Gomina Amosun laaye lati wọle sinu papa isere ti MKO Abiọla ti eto
ipolongo naa ti waye.
Bakan naa la tun gbọ pe ko pe
ti Gomina Amosun rawọ ẹbẹ si wọn pe ki wọn gba wọn laaye lati wọle la gbọ pe
wahala naa bẹrẹ, nigba tawọn to n ṣe ti adije sipo gomina labẹ ẹgbẹ oṣelu APM,
Ọnarebu Adekunle Akinlade naa bẹrẹ sii le awọn ọmọ ẹyin Dapọ Abiọdun jade.
Eyi ti wọn loo ya awọn eeyan
lẹnu ni bawọn ọlọpaa ko ṣe ri nnkankan ṣe si wahala naa, ti wọn si gba awọn
tọọgi laaye lati sọ okuta fun Aarẹ Buhari atawọn agbaagba ẹgbẹ oṣelu APC.
AWIKONKO gbọ pe Ọgbẹni Gbenga
Adeyanju ni Kọmiṣana tuntun ti wọn fi rọpo Ahmed Iliyasu lati ṣakoso eto aabo
ipinlẹ naa, paapaa fun idibo to n bọ lọna yi.
Ninu iwadii ti AWIKONKO ṣe la
ti gbọ pe bi idibo to n bọ lọna yi ko ba lọ bo ṣe yẹ, iyẹn ni pe bi eto aabo
awọn ọlọpaa ko ba daju, o ṣee ṣe ki wọn tun gbe Kọmiṣana tuntun naa kuro, ki
idibo gomina too waye nipinlẹ naa.
No comments:
Post a Comment