O MA ṢE O: ỌDAJU ABIYAMỌ FUN ỌMỌ Ẹ LỌRUN PA - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Saturday, February 16, 2019

O MA ṢE O: ỌDAJU ABIYAMỌ FUN ỌMỌ Ẹ LỌRUN PA

Bọsun Ọlaniyi, Abeokuta
O fẹẹ le jẹ pe gbogbo awọn to gbọ nipa iṣẹlẹ naa ni wọn n lo ohun gbogbo to wa nikawọ wọn lati fi ṣẹ epe nla-nla fun iyaale ile kan ta a ko tii mọ orukọ ẹ dasiko ta a ṣakojọpọ iroyin yi tan, latari bo ṣe fi okun fun ọmọ ẹ kan ṣoṣo lọrun pa.

Orileede Togo la gbọ pe iṣẹlẹ naa ti waye laipẹ yi, nigba ti wọn ni lẹyin gbọnmisi-omioto to waye laarin obinrin naa ati ọkọ ẹ lo bii ninu, to si wo o pe ọna kankan ṣoṣo to le mu koun fiya jẹ ọkọ oun ni lati pa ọmọ kan ṣoṣo to wa laarin wọn danu.

AWIKONKO gbọ pe inu ile kan nitosi ibi ti wọn n gbe ni obinrin naa lọọ fi okun fun ọmọ naa lọrun pa si, ko too di pe awọn araadugbo naa rọwọ to.

Iṣẹ eṣu la gbọ pe obinrin naa n kọ lorin pe o sun oun debẹ, ṣugbọn ti wọn lawọn ọlọpaa ti jẹ ko ye e pe, eṣu naa ni yoo sin de ọgba ẹwọn ti yoo ti lo eyitoku igbesi aye, iyẹn bi ile ẹjọ ko ba da ẹjọ iku fun un.


No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI