WỌN GUN ỌMỌBINRIN ARẸWA PA L'AKWA - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Wednesday, February 13, 2019

WỌN GUN ỌMỌBINRIN ARẸWA PA L'AKWA


Bọsun Ọlaniyi, Abeokuta

Kayeefi n’iku ọdọmọbinrin kan ti wọn pe oruọ rẹ ni Ezeobi Oluchukwu ṣi jẹ titi dasiko ti a ṣe akojọpọ iroyin yi tan pẹlu bawọn kan ta a ko tii mọ wọn, ṣugbọn tawọn ọlọpaa ṣi n ṣe iwadii wọn lọwọ ṣe gun un pa lọjọ Mọnde ijẹta.

Ohun ta a gbọ ni pe aarọ kutu lasiko ti Ezeobi tawọn eeyan tun n pe ni Luchy Belle n ṣe idaraya lọ lawọn ọdaran naa lọọ koju ẹ, iyẹn niluu Akwa, ipinlẹ Anambra, ti wọn si gun un pa.

Ezeobi ti wọn loo yan iṣẹ awọn to n ṣe oju loge laayo, ni wọn lawọn to pa a naa tun gba foonu rẹ salọ lẹyin ti wọn da ẹmi ẹ legbodo tan.

Mọṣuari kan to wa nitosi ibi ti wọn pa a si la gbọ pe awọn ọlọpaa gbe e lọ fun ayẹwo.

AWIKONKO gbọ pe lati bi ọjọ meloo kan sẹyin lawọn ọmọ ẹgbẹ okunkun ti n pa ara wọn danu, ti wọn tun n pawọn eeyan bo ṣe wu wọn, ta a si gbọ pe wọn ti pa eeyan ti ko din ni mẹfa bayii.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI