ỌṢUN: WỌN NI AJIBỌLA ATI ADEJARE N GBERO LATI KO TỌỌGI WOLU - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Friday, February 1, 2019

ỌṢUN: WỌN NI AJIBỌLA ATI ADEJARE N GBERO LATI KO TỌỌGI WOLU


Folukẹ Aduragbemi, Ọṣun

Ẹgbẹ oṣelu PDP ti ke gbajare si ọga ọlọpaa patapata lorileede yi, Mohammed Adamu pe ko tete gbe igbesẹ pajawiri lori wahala tawọ adije meji kan labẹ ẹgbẹ o’selu APC n fojoojumọ fa nipinlẹ naa.

Ọnarebu Adejare Bello ati Ọnarebu Ajibọla Baṣiru tawọn mejeeji n lọ fun ipo ọtọọtọ labẹ ẹgbẹ oṣelu APC ninu idibo to n bọ yi la gbọ pe wọn fojoojumọ fa wahala nipinlẹ naa, atipe wọn tun n gbero lati da wahala min in silẹ.

Adejare Bello, ti to figba kan ri jẹ abẹnugan ile igbimọ aṣofin nipinlẹ Ọṣun, to si tun jẹ oludije fun ipo ile igbimọ aṣofin apapọ orileede yii bayii fun agbegbe Ẹdẹ latinu, nigba ti Ajibọla n dije lati di Sẹnetọ fun ẹkun aaringbungbun Ọṣun labẹ ẹgbẹ APC kan naa.

Ninu atẹjade kan ti alaga ẹgbẹ PDP, Ọnarebu Sọji Adagunodo ati akọwe ẹgbẹ, Bọla Ajao fi sita ni wọn ti ni aṣiri ipade ikọkọ kan ti Adejare ati Ajibọla ṣe laipẹ yii ti tu sawọn lọwọ.

Ninu ipade naa ni wọn ti ni wọn fẹnuko lati lo awọn tọọgi lati kọlu mọto ipolongo Adagunodo ati ti Dọkita Deji Adeleke to jẹ ọkan lara awọn aṣaaju ninu ẹgbẹ PDP l'Ọṣun.

O fi kun atẹjade naa pe wọn ti dẹ awọn tọọgi silẹ lati ya bo awọn ẹgbẹ PDP nigba ti wọn ba lọọ ṣe ipolongo ibo, paapaa lagbegbe Ifẹlodun ati Oṣogbo.

Wọn wa ro ọga agba ọlọpaa lati ma ṣe fi ọrọ naa ṣere rara, ki wọn bẹrẹ iwadii kikun lori ẹ, ki wọn ma si ṣe faaye gba awọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu APC lati da wahala silẹ nipinlẹ Ọṣun ṣaaju, lasiko ati lẹyin idibo to n bọ yii.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI