AṢIRI OWO TẸGBẸ OṢELU APC NA NI KWARA LASIKO IDIBO TO KỌJA TU - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Saturday, March 2, 2019

AṢIRI OWO TẸGBẸ OṢELU APC NA NI KWARA LASIKO IDIBO TO KỌJA TU

Lasiko iṣẹlẹ naa
Ọlaide Ọṣinuga, Eko

Ijọba apapọ orileede Naijiria ti lawọn ko nii gba ki ajọ to n gbogun ti iwa jẹgudujẹra, EFCC ṣewadi owo ti wọn na lasiko idibo to kọja lo yi.

Ohun ta a gbọ ni pe lọjọ kẹẹdogun oṣu keji to kọja la gbọ pe wọn fẹẹ fi ọkọ ofurufu gbe owo naa lati ilu Eko lọ siluu Ilọrin nipinlẹ Kwara, ṣugbọn ti wọn sọ pe nibi towo naa pọ de, ọkọ ofurufu ko le gbe e.

AWIKONKO gbọ pe bi iroyin naa ṣe lu sita lawọn ajọ EFCC ti sare de bẹ, iyẹn ibi ti ọkọ ofurufu naa wa lati tọpinpin owo naa, gbogbo bi wọn ṣe sọ pe wọn beere ọrọ nipa owo naa ni ko sẹni to dahun, ṣugbọn tawọn kan pada sọ pe wọn fẹẹ lo owo naa fun idibo ni nipinlẹ Kwara ni.

Gbogbo bi wọn ṣe sọ pe awọn to n gbe owo naa lọ ṣe n foju bawọn oṣiṣẹ ajọ EFCC naa sọrọ pe awọn yoo fun wọn ninu ẹ bi wọn ba nifẹ sii, la gbọ pe wọn fariga pe ko si nnkan to jọ, ayafi tawọn ba gbe owo naa de ọfiisi wọn lati tubọ ṣewadi siwaju sii.

Ko pẹ la gbọ pe wọn pe awọn eeyan naa lori foonu lati ileeṣẹ Aarẹ orileede yi (Presidetial Villa) pe ki wọn gboju kuro nibẹ, ki wọn si panumọ, ati pe mẹnumọ ni ki wọn fi ọrọ naa ṣe.

AWIKONKO gbọ pe nibi ti wọn lawọn EFCC naa ti n bawọn ṣagidi pe awọn ko nii gba, la gbọ pe awọn ẹsọ ologun (soldier) ti de bẹ, ti wọn si halẹ mọ gbogbo wọn lasiko naa.

Awọn ẹsọ ologun naa la gbọ pe wọn pada jẹ ki wọn ko owo naa wọnu ọkọ ofurufuru min in, ti wọn fi gbe owo naa lọ ni nnkan bi aago mẹwa alẹ ọjọ naa.

Gbogbo akitiyan lati ba agbẹnusọ fun papakọ ofurufuru naa, Arabinrin Henrietta Yakubu sọrọ lo ja si pabo dasiko ta a sakojọpọ iroyin yi tan.

Bo tilẹ jẹ pe agbẹnusọ fujn ajọ EFCC, Ọgbẹni Tony Orilade sọ pe oun ri nnkan to jọ bẹ, ṣugbọn tawọn ko tii le fidi ẹ mulẹ, nitori pe o ṣee ṣe ko jẹ pe awọn ẹgbẹ alatako lo wa nidi ẹ, sibẹ, iwadi tun fi ye wa pe ko daju mọ pe ajọ EFCC yoo tubọ ṣewadi nipa owo naa.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI