AWỌN NNKAN TI Ẹ KO MỌ NIPA ỌBASANJỌ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Tuesday, March 5, 2019

AWỌN NNKAN TI Ẹ KO MỌ NIPA ỌBASANJỌ

Oluṣẹgun Ọbasanjọ
Asamọ kan lo ni ori lo mọ oloye, ori lo mọ ọlọla, ẹni ti yoo jẹ oriade ati ọrun ilẹkẹ si wa lọwọ ori.

Bẹẹ ni ọrọ ri pẹlu igbesi aye Oloye Matthew Olusẹgun Arẹmu Okikiọla Ọbasanjọ, ẹni to jẹ pe ọmọ orukan lasan ni lati igba to ti pe ẹni ọdun mọkalelogun amọ to pada wa di olori ilẹ Naijiria fun igba mẹta ọtọọtọ.

Igbesi aye akanda ẹda yii, ti awọn eeyan kan n pe ni Ẹbọra Owu, yẹ ko jẹ agbọkọgbọn ati awokọse fun awọn ọmọ Oodua nitori ẹsin iwaju ni tẹyin n wo sare.

Nibayii ti agba oselu ati eekan ọmọ ilẹ Kaarọ Oojire naa pe ẹni ọdun mejilelọgọrin loke eepẹ, BBC Yoruba lọ si ori itakun agbaye Wikipedia lati mọ nipa ilu mọọka ọmọ Yoruba yii, eyi to yẹ ki ẹyin naa mọ pẹlu.

Kí lo fẹ́ mọ̀ nípa Oluṣẹgun Ọbasanjọ?

  • Ọjọ Karun, osu Kẹta ọdun 1937 ni Oluṣẹgun dele aye, to si gba ilu Ibogun Ọlaogun, to wa lẹba ilu Abẹokuta nipinlẹ Ogun wọle
  • Baba rẹ lo n jẹ Amos Adigun Ọbaluayesanjọ Bankọle, eyi ti wọn n pe ni Ọbasanjọ bayii, ti iya rẹ si n jẹ Aṣabi
  • Ọdun 1958, nigba ti Oluṣẹgun wa ni ẹni ọdun mọkanlelogun, ni iya rẹ fi aye silẹ, ti baba rẹ naa si gba ọrun lọ lẹyin ọdun kan ti iya rẹ ku eyi to sọ di ọmọ orukan
  • Ile ẹkọ alakọbẹrẹ Saint David Ebenezer to wa ni Ibogun ni Oluṣẹgun lọ lọdun 1948, to si gba ibẹ rekọja sile ẹkọ girama Baptist Boys High School (BBHS) nilu Abẹokuta laarin ọdun 1952 si 1957
  • Ni kete to pari eto ẹkọ girama lo darapọ mọ ileesẹ ologun, to si lọ gba idanilẹkọ fun isẹ ologun kaakiri ilẹ Gẹẹsi ati lorilẹede India, to si bẹrẹ isẹ ologun nilu Kaduna ati Cameroon
  • Oluṣẹgun tun ba ajọ isọkan orilẹede agbaye (UN) sisẹ, to si wa lara awọn to lọ pẹtu sija lorilẹede Zaire, to di Congo lonii, ko to wa di ẹka imọ ẹrọ nileesẹ ologun mu lọdun 1963
  • Iṣẹ nla ni Olusẹgun se lasiko ogun abẹle Naijiria, taa mọ si Biafra, to si ja ogun naa ni ajasẹgun lọjọ Kejila, osu Kinni ọdun 1970
  • Osu Kinni ọdun 1975 ti Ọgagun Yakubu Gowon di olori orilẹede Naijiria lo yan Ọbasanjọ ni minisita fọrọ isẹ ode ati ilegbe
  • Nigba ti wọn gbẹmi Ọgagun Muritala Muhammed to gba akoso Naijiria lọwọ Gowon lọjọ Kẹtala, osu Keji ọdun 1976, ni wọ̀n yan Olusẹgun Ọbasanjọ gẹgẹ bii olori orilẹede yii
  • Lasiko ti Ọbasanjọ wa lori aleefa ni owo epo rọbi bu rẹkẹ pupọ, to si gbinyanju lati gbe olu ilu Naijiria kuro ni ilu Eko lọ si Abuja, eyi to fi Olusẹgun han bii ẹni ti kii se ẹlẹyamẹya
  • Lasiko isejọba ologun rẹ lo tun gbajumọ isẹ ọgbin lọpọ yanturu, to si se Operation Feed The Nation, eyi tii se eto Kebimapalu, oun naa si lo da ileesẹ aserin ni Ajaokuta silẹ
  • Ọbasanjọ tun se bẹbẹ lẹka eto ẹkọ pẹlu afikun awọn fasiti to wa nilẹ yii lati marun si mẹtala lọdun 1975
  • Ọbasanjọ huwa ta ni yoo mu mi lasiko to wa lori aleefa bii ologun, to si jo ile Fẹla Anikulapo Kuti kanlẹ, eyi to mu ẹmi iya Fẹla lọ
  • Ọbasanjọ fẹyin ti kuro nisẹ ologun lọjọ Kinni, osu Kẹwa ọdun 1979 nigba to fa akoso Naijiria fun ijọba alagbada ti Shehu Shagari dari rẹ
  • Lasiko isejọba Ọgagun Sani Abacha laarin ọdun 1993 si 1998, lo ran Olusẹgun ni ẹwọn ọgbọn ọdun lori ẹsun pe o dete lati fi tipa gba ijọba lọwọ oun
  • Inu ọgba ẹwọn yii ni Ọbasanjọ wa, to si di atunbi nigba to fi aye rẹ fun Jesu Kristi nibẹ, ko to ri idande kuro lẹwọn lẹyin iku Abacha
  • Lọdun 1999 ni Olusẹgun Ọbasanjọ pada di aarẹ orilẹede Naijiria lasiko eto iselu alagbada kẹrin, to si dije fun ipo aarẹ labẹ ẹgbẹ oselu SDP, bẹẹ lo se saa keji bii aarẹ lọdun 2003
  • Lasiko ti Ọbasanjọ jẹ aarẹ Naijiria ni ẹrọ ibaraẹnisọrọ alagbeka wọ Naijiria, o san awọn gbese ti Naijiria jẹ silẹ okeere, to si tun mu ki agbara owo naira si ti Dọla ni owura si
  • Olusẹgun gbogun nla ti iwa ajẹbanu, to si ka ileesẹ meji silẹ lati maa gbogun tiwa jẹgudu-jẹra, to si tun gbe ọpọ ileesẹ nla nla wa si Naijiria
  • Ọbasanjọ gbinyanju lati se saa kẹta lori aleefa, to si fẹ yi ofin ilẹ wa pada tori eyi, eyi to fa ija laarin rẹ ati igbakeji rẹ, Atiku Abubakar
  • Lẹyin to kuro ni aarẹ Naijiria, Ọbasanjọ di ẹni ọwọ jakejado agbaye, to si n leawaju awọn olori orilẹede miran yika agbaye
  • O maa n kopa to giriki ninu eto iselu Naijiria, to si maa n kọ oniruuru iwe si awọn olori to ba wa lori aleefa lati pe akiyesi wọn si awọn kudiẹ-kudiẹ kan ninu isejọba wọn
  • Baale ile ni Olusẹgun Ọbasanjọ, to si ni iyawo mẹrin. Orukọ wọn ni Esther Olurẹmi, Lynda (Oloogbe), Mojisọla Adekunle (Oloogbe) ati Stella Abebe toun naa ti di oloogbe
  • Ọmọ ogun ni Ọbasanjọ bi, lara wọn ni Iyabọ, Bisoye, Biyi, Bọla, Bukọla, Busọla, Damilọla, Dare, Dayọ, Deboye, Funkẹ, Funsọ, Gbenga, Juwọn, Kofo, Kunle, Olumuyiwa, Sẹgun, Seun ati Toyọsi
  • Ọpọlọpọ oye ni wọn ti fi da Olusẹgun Ọbasanjọ lọla, lara rẹ ni Balogun owu ati Ẹkẹrin Balogun Ẹgba, to si tun gba ọpọ ami ẹyẹ lati ilẹ okeere.
Diẹ lara awọn nkan ti Oluṣẹgun Ọbasanjọ ti gbe se loke eepẹ ree, ti ireti si wa pe yoo tun se ju bẹ lọ niwọn igba to si wa loke eepẹ.

Oluṣẹgun Ọbasanjọ 
O si yẹ ka fi igbe aye rẹ kọgbọn pe, laisi obi tabi ẹbi, sibẹ, o ta ara rẹ yọ lode aye lai gboju logun tabi ibatan kankan. 

A wa n gbaa ni adura bayii pe ọba oke yoo tubọ fun Oloye Oluṣẹgun Ọbasanjọ ni ẹmi gigun ati alaafia lati se ọpọlọpọ ọdun laye.

- BBC

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI