WỌN PARỌ MỌ MI NI O, MI O LE AJIMỌBI DANU O - TINUBU PARIWO SITA - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Tuesday, March 5, 2019

WỌN PARỌ MỌ MI NI O, MI O LE AJIMỌBI DANU O - TINUBU PARIWO SITA

Aṣiwaju ẹgbẹ oṣelu APC, Aṣiwaju Bọla Tinubu ti ni irọ ni iroyin to jade pe oun ti sọ fun gomina Ipinlẹ Ọyọ, Abiọla Ajimọbi ko ma ṣe farahan nibi ipolongo ibo gomina ẹgbẹ oṣelu naa.

Atẹjade kan lati ọwọ Tunde Rahman to jẹ oludamọran Tinubu lori ọrọ iroyin ni ko si ootọ kankan ninu iroyin kan to jade wi pe Tinubu gbe igbesẹ naa lori bi APC ko ṣe ṣe daadaa ninu idibo sile aṣofin agba ati ti Aarẹ, eyi to kọja lo.

Abiọla Ajimọbi nikan ni oludije fun ipo sẹnetọ ninu ẹgbẹ APC to fidirẹmi nipinlẹ Ọyọ.

Tinubu ninu ọrọ rẹ sọ pe, ko da, ọrẹ ni oun ati Ajimọbi, ati wi pe idi ti oun fi da si ọrọ APC ni Ọyọ ni lati ri wi pe ẹgbẹ naa ṣe daradara ninu idibo gomina to n bọ, kii ṣe wipe oun fẹ gba ipo lọwọ rẹ.

Atẹjade naa gbe ori yin fun Ajimọbi.

'O ti ṣe daradara ni Ọyọ ati wipe ohunkohun ti APC ba ri mu ni ipinlẹ naa, nitori Ajimọbi ni.'

O tun fi han wi pe nitori igbesẹ ti Tinubu gbe ni Ọyọ lo mu ki ọkan lara awọn oludije fun ipo gomina ni ipìnlẹ naa, Alao Akala pada si APC.

Tinubu ni iwe iroyin to gbe ofege iroyin naa nipa oun ati Ajimọbi jade kan fẹ sọ ọmọ iya meji di ọta ara wọn ni.

- BBC

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI