WỌN JI AKẸKỌỌ GBE FUN OOGUN OWO, ORI LO KO O YỌ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Monday, March 4, 2019

WỌN JI AKẸKỌỌ GBE FUN OOGUN OWO, ORI LO KO O YỌ

Ọmọ naa
Bọsun Ọlaniyi, Abẹokuta

Bi wọn ba a ṣadura pe ori wa ko nii gbabọde, adura to yẹ keeyan maa sare ṣe 'AMIN' nla si ni, nitori iru ọjọ ti yoo ba wulo.

Orin 'Ko s'Ọba bii 'rẹ' lawọn ara agbegbe kan nipinlẹ Delta mu sẹnu lọjọ Sande ana an nigba ti omodebinrin kan ti ọjọ ori ẹ ko tii ju ọdun mejila lọ sọ bi ori ṣe ko o yọ lọwọ awọn apanisoogun owo.

Gẹgẹ bi ọmọ naa ta a ko tii mọ orukọ ẹ dasiko ta ṣakojọpọ iroyin yi tan ṣe ṣalaye fawọn eeyan, o ni ko tii ju ọjọ diẹ lẹyin idibo ni wọn ji oun gbe lasiko toun lọ sile ẹkọ.

Ọmọ naa sọ pe nibi ti wọn ti fẹ ẹ ki ọbẹ bọ oun lọrun, ti wọn fẹ dunbu oun bi ẹran Ileya l'ẹnikan ti wa a sọ pe ori oun ko gbabọde, nitori naa ki wọn da oun pada.

Ṣe lawọn to wa nibi tọmọdebinrin naa ti n tu aṣiri yi bẹrẹ sii jo, ti wọn si n kii ku oriire ko too di pe wọn muu lọ fawọn obi ẹ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI