ẸGBẸ OṢELU APC N GBIYANJU LATI DA WAHALA SILẸ L’OGBOMỌṢỌ - MAKINDE PARIWO SITA - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Saturday, March 2, 2019

ẸGBẸ OṢELU APC N GBIYANJU LATI DA WAHALA SILẸ L’OGBOMỌṢỌ - MAKINDE PARIWO SITA

APC Planning To Cause Mayhem In Ogbomoso, Oke-Ogun, Other PDP Strongholds - Makinde
Ọla Eyitayọ, Ọyọ 

Adije sipo Gomina labẹ ẹgbẹ oṣelu PDP, Ọgbẹni Ṣeyi Makinde ti pariwo sita pẹlu ẹsun to fi kan ẹgbẹ oṣelu APC pe wọn n gbiyanju lati da wahala nla silẹ nipinlẹ Ọyọ, paapaa lawọn ilu bii Ogbomọṣọ, Ibarapa, Oke-Ogun atawọn ilu tẹgbẹ oṣelu PDP ti lẹnu ju wọn lọ fun idibo ọsẹ to n bọ.

O ni gbogbo igbesẹ tẹgbẹ oṣelu APC to wa nijọba bayii n gbe ni pe ki wọn da idibo naa ru, ki ajọ eleto idibo, INEC le sọ pe idibo ko pari, ati pe atundi ibo yoo waye, eyi ti wọn n pe ni inconclusive, gẹgẹ bo ṣe waye nipinlẹ Ọṣun lọdun to kọja

Ninu atẹjade ti agbẹnusọ olupolongo idibo ẹ, Ọmọba Dọtun Oyelade gbe sita lonii, o ni lara awọn ẹgbẹ onimọto ti National Union of Road Transport Workers (NURTW) ti lọ n halẹ mọ awọn ọlọja atawọn araalu pẹ dandan ni ki wọn dibo fun ẹgbẹ APC lopin ọsẹ to n bọ naa.

O lawọn agbegbe bii Ogbomọṣọ, Ibadan, Ibarapa ati Oke-Ọgun ni wọn ti n dunkoko mọ awọn eeyan, ati pe awọn agbegbe naa lẹgbẹ oṣelu PDP ti lẹnu ju wọn lọ.

Ọmọba Oyelade jẹ ko di mimọ pe pẹlu awọn igbesẹ tẹgbẹ naa tun n gbe bayii, o ṣee ṣe ko jẹ pe awọn ẹrọ ti wọn fi n ṣayẹwo kaadi idibo ti ko nii ṣiṣẹ ni wọn maa gbe wa sawọn agbegbe idibo lọjọ naa, lati ma jẹ kawọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu PDP ri ibo di, gẹgẹ bo ṣe ṣẹlẹ lọjọ Satide to kọja lọ nilẹ Awusa.

Nigba to n fọkan awọn araalu balẹ, Ṣeyi Makinde sọ pe oun nigbagbọ pe ẹgbẹ oṣelu PDP yoo rọwọ mu gidi nitori pe pẹlu maaki rẹpẹtẹ lawọn yoo fi la ẹgbẹ oṣelu APC lọjọ naa, nitori naa, o ni kawọn araalu jade lọpọ yanturu lati dibo lọjọ naa.

Bẹẹ lo wa rọ ajọ INEC atawọn ileeṣẹ eleto aabo pe ki wọn ma ṣe ṣe oju-ṣaaju lọjọ naa.No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI