O PARI: GOMINA AMOSUN FI ẸGBẸ OṢELU APC SILẸ, O TI BA APM LỌ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Sunday, March 3, 2019

O PARI: GOMINA AMOSUN FI ẸGBẸ OṢELU APC SILẸ, O TI BA APM LỌ


Ọlaide Ọṣinuga, Eko

Kii ṣe iroyin tuntun mọ pe Gomina ipinlẹ Ogun, Ibikunle Amosun ti ẹgbẹ oṣelu APC lati ọjọ Wẹside ọsẹ to kọja yi ti n ṣiṣẹ takun-takun lati rii pe adije sipo Gomina labẹ asia ẹgbẹ oṣelu APM, Ọnọrebu Adekunle Akinlade yege ninu idibo to n bọ lọjọ Satide ọsẹ yi, iyẹn ọjọ kẹsan an oṣu kẹta ta a wa yi.

Latigba ti Gomina Amosun ti jawe olubori ninu idibo apapọ to kọja gẹgẹ bi i Sẹnetọ ti yoo ṣoju Aaringbungbun ipinlẹ naa labẹ asia ẹgbẹ APC lo ti bọ aṣọ ẹgbẹ naa danu s'ẹgbẹ kan, to n gbe asia ẹgbẹ oṣelu APM kaakiri.

Bo tilẹ jẹ pe apapọ ẹgbẹ oṣelu APC ati igbimọ amuṣẹṣe, NWC ẹgbẹ naa ti jawe lọọ gbele ẹ fun Gomina Amosun pe awọn ko fẹẹ ri i mọ ninu ẹgbẹ latari ẹsun iwa agabangebe ti wọn fi kan an.

Pẹlu bi Gomina Amosun ṣe n lọ kaakiri gbogbo ijọba ibilẹ to wa nipinlẹ Ogun lati polongo ibo fun Ọnọrebu Akinlade ni ko jẹ k'awọn araalu ṣe iyemeji pe o ti f'ẹgbẹ naa silẹ.
Ati pe latigba ti apapọ ẹgbẹ oṣelu APC ti sọ pe awọn ti da a duro ninu ẹgbẹ ni ko ti sọ nnkankan si i, yala lati bẹbẹ tabi da a pada fun wọn pe ko sẹni to le le oun.

Kaka ki Gomina Amosun sọrọ tako aṣẹ ẹgbẹ APC fun bi wọn ṣe lawọn ti le e, ipolongo bi ẹgbẹ oṣelu APM yoo ṣe wọle idibo to n bọ lọna lo n ba kaakiri.

Idi pataki tawọn eeyan fi n sọ pe Gomina Amosun ko si ninu ẹgbẹ naa mọ, wọn loo ti ba ẹgbẹ APM lọ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI