ITIJU NLA; WỌN JA SẸNETỌ SIHOHO L'ABUJA - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Sunday, March 3, 2019

ITIJU NLA; WỌN JA SẸNETỌ SIHOHO L'ABUJA

Iyalẹnu lọrọ Sẹnetọ ti wọn ṣẹṣẹ dibo yan labẹ asia ẹgbẹ oṣelu APC nipinlẹ Nassarawa, Ọnọrebu Godiya Akwashiki ṣi n jẹ fawọn ọmọ orileede Naijiria, paapaa gbogbo awọn ti wọn ri fọnran nibi ti wọn ti ja a sihoho ọmọluabi lalẹ ọjọ Satide Abamẹta ana an.

Ilu Abuja la gbọ pe aṣiri Ọnọrebu Godiya Akwashiki ti tu lakooko ti wọn ka nibi to ti n ko ibasun fun iyawo-oniyawo, to tun jẹ iyawo ọkan lara awọn gbajumọ oloṣelu nipinlẹ Nassarawa.

Baṣiri ẹ ṣe tu la gbọ pe awọn gendekunrin ti wọn wa nitosi ti bere sii luu, ti wọn si ja a sihoho lẹsẹkẹsẹ.

AWIKONKO gbọ pe igbakeji abẹnugọn ile igbimọ aṣofin ipinlẹ Nassarawa ni Ọnọrebu Godiya, to si gbe apoti dupo Sẹnetọ, t'awọn eeyan si dibo fun ninu idibo to kọja yi.

Titi dasiko ta a ṣakojọpọ iroyin yi tan, teṣan ọlọpaa ti Maitama niluu Abuja la gbọ pe Ọnọrebu naa wa bayii, nibi ti wọn ti n f'ọrọ wa a lẹnu wo.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI