NITORI IKU ṢỌJA MEJI, AWỌN EEYAN SA KURO NILUU - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Monday, March 4, 2019

NITORI IKU ṢỌJA MEJI, AWỌN EEYAN SA KURO NILUU

Ọlaide Ọṣinuga, Eko

Ṣe ni idaamu nla bawọn olugbe agbegbe Abonnema nijọba ibilẹ Akuku-Toru, ipinlẹ Rivers laarọ ana Sande nigba ti wọn lawọn ẹṣọ ologun, ṣọja ya wọ agbegbe naa lati gbẹsan iku meji lara wọn.

AWIKONKO gbọ pe lopin ọsẹ to kọja yi, iyẹn ọjọ Satide Abamẹta la gbọ pe wọn ṣadede ri oku awọn ṣọja meji kan ti wọn gbe lọ sagbegbe naa lasiko idibo lẹgbẹ titi.

Kii ṣe pe wọn pa awọn ṣọja yi nikan gẹgẹ ba a ṣe gbọ, wọn ni wọn tun ko ibọn ti wọn fi n ṣiṣẹ salọ pẹlu, ti ko si ti i sẹni to le sọ bi iku awọn ṣọja naa ṣe waye titi dasiko ta ṣakojọpọ iroyin yi tan.

Latigba ti ijọba apapọ orileede yi ti paṣẹ pe k'awọn ṣọja gbakoso eto aabo lasiko idibo to kọja la gbọ pe awọn ṣọja naa ti wa lagbegbe Abonnema ti wọn pin wọn si.

Aditu la gbọ iku awọn ṣọja naa jẹ nitori ti ko tii sẹni to le sọ pato nipa bi wọn ṣe ku, ṣugbọn ta a gbọ pe iwadii n lọ lọwọ.

Lọjọ Satide Abamẹta naa la gbọ pe awọn abiyamọ agbegbe naa jade sita lati fẹhonu han nipa bi wọn ṣe pawọn ọmọ marundinlogoji (35) lasiko idibo to kọja.

Laarọ Sande la ri i pe awọn eeyan n ko ẹru wọn kuro lagbegbe naa lati sa asala fun ẹmi ara wọn, nitori igbagbọ wọn pe awọn ṣọja n bọ wa gbẹsan iku awọn meji naa, to si ṣee ṣe ki alaiṣẹ naa fara gba nibẹ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI