MI O NII GBA, ILE ẸJỌ KOTẸMILỌRUN NI YOO PARI Ẹ - GOMINA OYETỌLA - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Friday, March 22, 2019

MI O NII GBA, ILE ẸJỌ KOTẸMILỌRUN NI YOO PARI Ẹ - GOMINA OYETỌLA

Gomina ipinlẹ Ọṣun, Alaaji Gboyega Oyetọla ti sọ pe oun ko nii gba ki wọn yan oun jẹ, ki wọn si le oun kuro nipo Gomina toun ti n gbadun lati bii oṣu mẹfa sẹyin, t'awọn araalu si ti n kan saara soun nipa awọn akanṣe iṣẹ manigbagbe toun dawọ le.

Lonii ọjọ Fraide ni ile ẹjọ Tribunal to fikalẹ siluu Abuja so pe ki Alaaji Gboyega Oyetọla to ti wa nipo Gomina ipinlẹ Ọṣun fi ipo naa silẹ ni kiakia, ko si da iwe ẹri to gba lọwọ ajọ INEC pada fun Sẹnetọ Ademọla Adeleke nitori pe oun gan an lẹri fi han pe oun jawe olubori ninu idibo to waye ninu oṣu kẹsan an ọdun 2018.

Lẹsẹkẹsẹ ti aṣẹ naa ti jade sita ni akọwe ijọba ipinlẹ naa, Ọgbẹni Wọle Oyebamiji ti gbe atẹjade sita pe ko si nnkan to jọọ, afi ki ile ẹjọ Kotẹmilọrun b'awọn da sii.

Ninu atẹjade naa lo ti sọ pe "Ijọba ipinlẹ Ọṣun fẹẹ fi asiko yi dupẹ lọwọ gbogbo awọn to gbaruku ti ijọba oun lati rii pe idagbasoke ati ilọsiwaju nipa ifọwọsowọpọ n ṣẹlẹ.

"Bo ṣe wa bayii, ijọba ọlọlajulọ Ọgbẹni Adegboyega Oyetọla, Gomina ipinlẹ Ọṣun fẹẹ fi da awọn eeyan loju pe idajọ ti ile ẹjọ Tribunal gbe kalẹ lawọn ti wa nnkan ṣe si, t'awọn si ti pe ẹjọ Kotẹmilọrun lori ẹ.

"Eyi ni lati tun fi dawọn olugbe ipinlẹ Ọṣun loju pe aabo ẹmi ati dukia to peye yoo wa fawọn eeyan , nitori pe ijọba ipinlẹ naa ni ojulowo ijọba to ni aṣẹ lati dari ipinlẹ naa lọwọ.

"A fi n dawọn eeyan wa loju pe otitọ yoo leke nigbẹyin, ati pe gbogbo awọn agbofinro lati sọ fun pe ki wọn bọwọ fun ofin kaakiri ipinlẹ yi.

"Ni bayii, a n rọ gbogbo awọn olugbe pe ki wọn jade lati ṣe ojuṣe wọn labẹ ofin lai ni idaduro kankan. A dupẹ lọwọ yin."

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI