GBAJUMỌ SỌFIYỌ DI AṢIWAJU ILU OGERE-RẸMỌ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Friday, April 19, 2019

GBAJUMỌ SỌFIYỌ DI AṢIWAJU ILU OGERE-RẸMỌ

Bi ẹ ṣe n ka iroyin yi, gbogbo eto lo ti fẹẹ pari bayii fun ti ayẹyẹ igboye tuntun ti ọkan lara awọn agba gbajumọ to mọ nipa ọrọ ilẹ daadaa nipinlẹ Ogun, paapaa lorileede Naijirai, Oloye Sọlomọn Oluṣẹgun Adeniyi lọjọ Satide ọsẹ to n bọ, iyẹn ọjọ kẹtadinlọgbọn, oṣu kẹrin ti a wa yi.

Gẹgẹ bi iroyin to tẹ AWIKONKO lọwọ, a gbọ pe Ọba Ọladele Ogungbade, Agbejoye II, to jẹ Ologere tiluu Ogere Rẹmọ lo fi oye naa da Oloye Adeniyi lọla fun akitiyan rẹ nipa idagbasoke ilu Ogere, paapaa ipinlẹ Ogun lapapọ.

Eto igboye naa la gb'ọ pe yoo bẹrẹ laago mọkanla aarọ nigba ti yoo lọ ọ gba iwure laafin Ologere tiluu Ogere, ti wọn yoo si kadi ayẹyẹ nla naa pẹlu eto ọlọkan-o-jọkan ni gbagede ileewe girama ti ọṣitẹlu.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI