O MA ṢE O: GBAJUMỌ OLORIN APALA NNI, MUSILIU HARUNA IṢỌLA PADANU IYAWO Ẹ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Tuesday, April 23, 2019

O MA ṢE O: GBAJUMỌ OLORIN APALA NNI, MUSILIU HARUNA IṢỌLA PADANU IYAWO Ẹ

Bi ẹ ṣe n ka iroyin yi, inu ibanujẹ nla ni gbajumọ olorin apala nni, Oloye Musiliu Haruna Iṣọla ti padanu iyawo ẹ, Alaaja Ajebọ Iṣọla.

Bo tilẹ jẹ pe a ko ti i le fidi nnkan to pa Alaaja Ajebọ, ṣugbọn ohun ta a gbọ ni pe oru mọju ni Obinrin naa dagbere faye.

Ọkan lara awọn to fiṣẹlẹ naa to wa leti jẹ ko ye wa pe oun si ri obinrin naa lọjọ Tọside to kọja yi, ti ko si sapẹrẹ pe o n ṣaisan.

Ẹkunrẹrẹ iroyin naa n bọ laipẹ. Ki Ọlọrun ba wa tu gbajumọ olorin naa atawọn mọlẹbi wọn lọkan, ko si tẹ Alaaja Ajebọ safẹfẹ rere. Amin.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI