WAHALA DE O: IPAC IPINLẸ OGUN YỌ ARABAMBI GẸGẸ BI ALAGA FUNGBA DIẸ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Wednesday, April 24, 2019

WAHALA DE O: IPAC IPINLẸ OGUN YỌ ARABAMBI GẸGẸ BI ALAGA FUNGBA DIẸ

Bọsun Ọlaniyi, Abẹokuta: Bi ẹ ṣe n ka iroyin yi, ko daju pe apapọ awọn alaga ẹgbẹ oṣelu kaakiri ipinlẹ Ogun, iyẹn IPAC yoo da Kọmureedi Abayọmi Arabambi pada sipo alaga ẹgbẹ naa latari bi wọn ṣe yọ ọ lojiji.

Oni ti i ṣe ọjọ kẹrinlelogun oṣu kẹrin ni ẹgbẹ naa ṣepade nile ẹgbẹ oṣelu MEGA to wa lagbegbe Akin-Olugbade, Abẹokuta.

Gẹgẹ ba a ṣe gbo, wọn ni latari awọn aṣemaṣe ti Abayọmi Arabambi n ṣe ninu ẹgbẹ naa, paapaa gẹgẹ bi alaga lo mu ki wọn gbe igbesẹ pe ko lọọ rọkunle fungba diẹ.

Lẹsẹkẹsẹ ti wọn gbe igbesẹ yi naa la gbọ pe wọn tun ti paṣẹ pe kawọn igbimọ to n fiya jẹ ẹlẹṣẹ, iyẹn Disciplinary Committee ti wọn yan bẹrẹ igbesẹ lati ṣe iwadii Arabambi lori awọn ẹsun oriṣiriṣi ti wọn fi kan an.

AWIKONKO gbọ pe Kọmureedi Abayọmi Arabambi to jẹ alaga ẹgbẹ yi ni wọn loo pe ipade naa lonii, to si fi lẹta to bu ọwọ lu ranṣẹ si gbogbo awọn ọmọ ẹgbẹ patapata kaakiri ipinlẹ Ogun, ko si ju bi i iṣẹju mẹwaa ki ipade ti wọn pe si aago mẹwaa aarọ bẹrẹ ni wọn ni Arabambi fi atẹjiṣẹ ranṣẹ si gbogbo wọn pe ipade naa ko ni le waye mọ.

Wọn ni pupọ ninu awọn ọmọ ẹgbẹ naa ni wọn ki i gbe Abẹokuta, to jẹ pe kaakiri ipinlẹ Ogun ni onikaluku wọn ti wa, to si jẹ pe gbogbo wọn ni wọn ti jokoo sibi ipade naa, ki Arabambi to o sọ pe ipade ko ni le waye mọ.

Pẹlu iwe ofin ẹgbẹ naa to sọ pe bi alaga ko ba si nile, igbakeji ẹ le dari ipade to ba waye lo mu ki wọn ṣe ipade naa, ti wọn si fẹsun oriṣiriṣi kan Arabambi, eyi ti wọn loo lo ipo ẹ lati ṣe aṣemaṣe, ti ko si tun fi nnkan to n lọ ninu ẹgbẹ na to awọn ọmọ ẹgbẹ leti.

Nigba to n sọrọ, Kọmureedi Olufẹmi to jẹ alaga ẹgbẹ oṣelu Better Nigeria Progressive Party, to tun jẹ alaga awọn to n pẹtu si aawọ ninu ẹgbẹ naa ti wọn ṣẹṣẹ yan sọ pe "Ninu ipade ta a ṣe lonii, gbogbo ọmọ ẹgbẹ lo wa nikalẹ, tonikalu si fi oriṣiriṣi ẹsun kan Kọmreedi Arabambi lori pe ko jẹ kawọn ọmọ ẹgbẹ ri nnkan to n lọ ninu ẹgbẹ, to si tun n pa irọ, oun la ṣe fẹnuko pe ka tare ẹ si ọdọ awọn to n ṣewadii, iyẹn Discplinary committee.

"Oriṣi iwe ẹsun mẹta ọtọọtọ ni wọn mu wa, paapaa ninu ẹgbẹ tiẹ to n ṣe, eyi to jẹ Labour. a ko si le fi ina sori orule sun, ki ẹgbẹ IPAC to o le lọ siwaju, a gbọdọ gbe ilana kalẹ la ṣe fẹnuko pe a fi ki Arabambi lọọ jokoo sile naa, lati le ṣewadi awọn ẹsun ti wọn fi kan an yi.

"Emi ro pe arifin nla ati aikanikun ni igbesẹ ti Arabambi gbe lati sọ pe o da ipade nu. Alaga funra ẹ lo pe ipade lori awọn kọmiti ti a fẹ ẹ yan lonii, to si bu ọwọ luu pe ka maa bọ. A ti pejọpọ lati bẹrẹ ipade ko too bẹrẹ si i fi atẹjiṣẹ ranṣẹ pe oun ko fẹẹ wa nitori pe awọn kan n fi iku wa oun kaakiri. Bibeli sọ pe bi iwọ ba ṣe rere, ara ki o a ya ọ bi.

"Idibo ti kọja, o si ti lọ, a si ri i pe oriṣiriṣi ọna ati igbesẹ ti ko tọ ni Arabambi gbe, ta a si pe ipade pe ko wa a ṣalaye ara ẹ. Ile gbọrọmiro nile ẹjọ, iwe ofin wa fun wa to gbe wa lẹyin, ko gbiyanju lati lọ"

Bakan naa nigba toun naa n sọrọ, Kọmureedi Bọla Oyedele to jẹ alaga ẹgbẹ oṣelu Peoples Party of Nigeria, PPN nipinlẹ Ogun sọ pe "Bi alaga ta a ṣẹṣẹ yọ yi ṣe loun sun ipade siwaju lo da awuyewuye silẹ. Aggọ mẹwa lo yẹ ka bẹrẹ ipade, ta a si ti pejọ, ko da ti amugbalẹgbẹ Kọmureedi Arabambi naa tun wa nibẹ, lẹyin bi i wakati kan lo to o ṣẹṣẹ fi atẹjiṣẹ ranṣẹ si wa pe oun ti sun ipade siwaju.

"Bi gbogbo laga ẹgbẹ oṣelu patapata ba wa nibi kan, ti ẹnikan ṣoṣo ba wa sọ pe ẹmi oun wa ninu ewu, o tunmọ si pe awọn ara ipinlẹ Ogun ko si labẹ aabo to peye niyẹn, a si gbọdọ jẹ kawọn eeyan mọ pe aabo to peye lo wa nipinlẹ Ogun ta a wa yi.

"To ba fẹ sun ipade siwaju, o yẹ ko ti fi to wa leti lati bi i wakati mejidinlaadọta (48hours) tabi wakati mẹrinlelogun (24hours). Ṣe lo foju di gbogbo wa patapata, nitori pe alaga ẹgbẹ oṣelu kọọkan ni gbogbo wa, ta a si pawọpọ lati fi sibẹ, ko yẹ ko ri bẹẹ."

Ninu ọrọ ti alaga fidihẹ ti wọn yan, Alaaji Mọshood Adeṣhina ni "Ko si nnkan to jọ pe ki ẹnikan pade eeyan kan nile ẹjọ nitori pe a ti yan igbimọ nitori pe awa ta a wa nibi ipade yi pọ ju awọn ti ko si nibẹ lọ, ti ofin si wa fun un. Ki i ṣe pe wọn yọ Araba,bi lailai, fungba diẹ ni wọn fi sọ pe ko ṣi lọ jokoo sile naa, nitori pe alaga ko le wa lori ipo lasiko ti wọn n ṣewadi lọwọ

"A tẹle ofin ati ilana to de wa. A ko le wa bayii ki ẹgbẹ ma ni olori lo mu kile panupọ lati yan mi gẹgẹ bi alaga fidihẹ."

Nigba to n tako ẹsun ti wọn fi kan an, ati bi wọn ṣe yọ ọ, Kọmureedi Abayọmi Arabambi ninu ọrọ sọ pe awada kẹrikẹri ni wọn n ṣe nitori pe ko sẹni to to bẹẹ lati yọ oun nipo, nitori pe ipade ti wọn ṣe naa, oun loun pe e, toun si tun ti sun un siwaju pe ipade naa ko le waye mọ.

Arabambi sọ pe, nnkan toun mọ daju ni pe Ọmọba Buruji Kaṣamu ati Ọmọba Dapọ Abiọdun ni wọn wa nidi igbesẹ tawọn ọlọtẹ ninu ẹgbẹ IPAC naa gbe, nitori pe ọpọ igba lawọn mejeeji yi pe oun pe koun wa a gba owo lati le yọwọ kuro ninu ẹjọ Tribunal toun pe.

O tun sọ ninu ọrọ rẹ pe ọgọrun miliọnu naira ni Ọmọba Buruji Kaṣamu fi n bẹ oun lati yọwọ ninu ẹjọ naa, ti Ọmọba Dapọ Abiọdun naa si n fi obitibiti owo lọ oun, lati le pana ẹjọ to n lọ lọwọ ni Tribunal.

Siwaju si i ninu ọrọ rẹ, o ni "Lootọ, emi ni mo pe ipade yi, ti mo si fi lẹta ranṣẹ si gbogbo awọn ọmọ ẹgbẹ, ṣugbọn nigba ti mo gbọ pe ṣe ni wọn fẹẹ pa mi, lo jẹ ki n sọ pe ka sun ipade naa siwaju. Ọgbẹni Olufẹmi Oluṣẹgun to jẹ alaga ẹgbẹ oṣelu BMPP ati Ọgbẹni Mọshood Adeṣhina toun jẹ alaga ẹgbẹ oṣelu Mẹga ni wọn gbimọ lati gba ẹmi mi lonii, ti mo si sa asala fun ẹmi mi."

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI