AṢIRI WAHEED ATAWỌN ỌRẸ Ẹ TO N JI PATA KA TI TU O - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Sunday, May 12, 2019

AṢIRI WAHEED ATAWỌN ỌRẸ Ẹ TO N JI PATA KA TI TU O

Ṣe ni gbogbo awọn araalu Agbọwa lagbegbe Ogijo, ipinlẹ Ogun gbe igba ilu ati ijo, ti wọn n kọrin yika ilu nigba tọwọ ọlọpaa tẹ awọn ogbologbo ọmọ ẹgbẹ okunkun Eiye ti wọn tun n ji pata ka.

Awọn kan la gbọ pe wọn ta awọn ọlọpaa lolobo pe awọn kofiri awọn ọdaran naa nibi ti wọn ti n ṣepade lọwọ, eyi lo mu ki wọn gbera lati lọọ raga bo wọn, taṣiri wọn si tu.

Awọn ọdaran mẹta tọwọ tẹ naa ni Ọlagboye Abidemi, ẹni ọdun mejilelọgbọn; Ọlasmj Michael, ọmọdun mejidinlọgbọn ati Wasiu Waheed toun jẹ ọmọdun mẹtalelogun.

Lara awọn nnkan ti wọn gba lọwọ wọn ni ọbẹ ti wọn ṣẹṣẹ fi gun eeyan tan, ada alaamu, pata obinrin ti wọn foogun yi atawọn oogun min in loriṣiriṣi.

Gẹgẹ bi Abimbọla Oyeyẹmi ṣe ṣalaye f’AWIKONKO, o lawọn ọdaran naa ko ni i pẹ foju bale ẹjọ latari aṣẹ kọmiṣana wọn, Bashir Makama.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI