MAN CITY GBOMIJE IBANUJẸ LOJU LIVERPOOL, WỌN GBA LIIGI PREMIERSHIP - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Sunday, May 12, 2019

MAN CITY GBOMIJE IBANUJẸ LOJU LIVERPOOL, WỌN GBA LIIGI PREMIERSHIP

Bi eeyan ba n ṣe iyemeji tẹlẹ, ko si aniani mọ, Manchester City ti gba ife ẹyẹ Liigi Premiership ti ọdun yi.

Manchester City jẹwọ pe ẹni a ba ni aba ni Baba fun Liverpool pẹlu bi wọn ṣe din dundun iya mẹrin si odo fun Brighton.

Gundogan lo jẹ goolu kẹrin pẹlu gbe silẹ gba sile to gba wọ ile Brighton.

Kete ti goolu naa wọle ni gbogbo agbo daru ti awọn alatilẹyin City si bẹrẹ si ni jojo ayọ.

Abala Ikeji ti bẹrẹ

Nigba ti a ba fi ri iṣẹju márùndínláàdọ́ta tabi ju bẹ lọ diẹ a o mọ ẹgbẹ agbabọọlu ti yoo gba ife ẹyẹ Premiership ti ọdun yi.

Laarin Liverpool ati Manchester City ni dugbẹ dugbẹ yi n fi si amọ ko ti daju ibi ti yoo ja si.

Bi abala Ikini ti ṣe lọ

Nkan kọkọ fẹ jọbi pe ko ṣẹnu re fun ẹgbẹ agbabọọlu Manchester City ninu ifẹsẹwọnṣẹ to n lọ lọwọ ninu idije Premiership.

Amọ nigba ti awọn agbabọọlu wọn yoo fi ṣara giri, wọn fi goolu meji si ookan ti Brighton fi ẹsẹ rinlẹ lori afara liigi Premiership.

Akẹgbẹ wọn Liverpool n tọ wọn lẹyin pẹlu bi wọn ti ṣe fi goolu kan ju Wolves lọ.

Sadio Mane lo jẹ goolu naa fun Liverpool.

Bi nnkan ti ṣe ri bayi, Manchester City lo jọ bi pe wọn yoo gba ife naa.
 aworan afara liigi
Ninu awọn ifẹsẹwọnsẹ miran to n waye wọn yi ni esi ti a ri ni abala kini

    Brighton1 Man City 2

    Burnley 0 Arsenal0

    Crystal Palace 3 Bournemouth 0

    Fulham 0 Newcastle 2

    Leicester0 Chelsea 0

    Liverpool 1 Wolves 0

- BBC

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI