Aarẹ Ẹgbẹ Igbimọ Ọdọ Yoruba
l'Agbaye (Yoruba Council of Youths Worldwide), Arẹmọ (Amofin) Ọladọtun
Hassan ti sọ pe afi ki Aarẹ orileede Naijiria, ọgagun Muhammadu Buhari tete
bawọn ṣepade lati wa ọna abayọ sawọn iṣoro to n koju eto aabo lorileede yi ko
too pẹ ju.
Arẹmọ Ọladọtun Hassan lo sọrọ yi
ninu atẹjade to gbe sita lopin ọsẹ to kọja yi, iyẹn Satide ana, eyi ti ẹda ẹ tẹ
AWIKONKO lọwọ loni in, nibi to ti sọ pe ọrọ aini eto aabo to peye lorileede
Naijiria lasiko jẹ ohun to n kan ohun lominu pupọ, tawọn si gbọdọ wa iyanju si i.
Ninu atẹjade naa ni Aarẹ
Ọladọtun Hassan to tun jẹ Amofin to gbona nidi iṣẹ ofin nigba to n mẹnuba diẹ
lara awọn iṣoro to n koju eto aabo sọ pe ipade ti Aarẹ Buhari ba bawọn ṣe ni
yoo tọka sawọn ọna abayọ.
Lara awọn iṣoro naa gẹgẹ bo ṣe
mẹnuba wọn ni: Wahala awọn Fulani darandaran; bawọn ọlọpaa ṣe lo n kogun ja
awọn eeyan ti wọn si tun n fipa bawọn obinrin laṣepọ, paapaa eyi to waye niluu
Abuja laipẹ yi; aijẹ kawọn araalu ja fun ẹtọ wọn, to si n mu ẹmi ọpọ awọn lọ, nipasẹ
alaanu to pọ lọwọ awọn ọlọpaa.
Awọn min in ni: aisi eto aabo
nla lawọn opopona kaakiri bii Kaduna, Ijẹbu-Ode, Benin si Ọrẹ atawọn min in to
si n fa ijinigbe ati ole jija; bawọn apani-ṣowo ṣe dẹmi awọn eeyan legbodo, ati
bawọn to n fiṣẹ gbajuẹ ori ayelujara pawọn eeyan ṣowo, ti wọn si tun lu awọn
eeyan ni jibiti loriṣiriṣi abbl.
Bakan naa lo tun mẹnuba iṣẹ ati
oṣi to n bawọn araalu finra, ti iwa ajẹbanu si n peleke si lojoojumọ, ko da ti
airiṣẹṣe awọn ọdọ gan an ko gbẹyin, ati oogun ẹlẹyamẹya, ti ijọba apapọ naa si
gbagbe awọn ileri ti wọn bawọn araalu ṣe.
Bẹẹ lo tun mẹnuba awọn to n da
ogun silẹ, eyi ti Myetti Allah n sọ si ẹgbẹ Afẹnifẹre ati ẹgbẹ Indigbo, tijọba
apapọ ko si wa nnkan ṣe si i. Ati pe eyi to tun ba gbogbo ẹ jẹ ni ijọba apapọ
tun ṣe ṣeleri ọgọrun biliọnu naira fawọn Fulani darandaran.
Arẹmọ Hassan lawọn nnkan wọnyi
lo n ṣakoba fun eto aabo, to si nilo agbeyẹwo ni kiakia ko o di pe oogun ailero
yoo ṣẹlẹ. Idi ni yii to fi sọ pe ki Aarẹ Buhari tete bawọn ṣepade ti yoo jẹ
kawọn iṣoro naa di ohun igbagbe.
O ni asiko to dara julọ re e
lati ṣe agbeyẹwo ọna ti a n gba ṣejọba lati le ṣe atunto pẹlu ofin tuntun ti
yoo fun awọn ẹlẹkunjẹkun lagbara ninu ijọba.
O sọ pe ṣaaju oṣu kẹjọ ọdun yi
ti Aarẹ Buhari yoo ṣagbatẹru eto to nii ṣe pẹlu alaafia niluu Abuja, ko tete
bawọn adari YCYW ṣe ipade, lati le ba a jiroro lori awọn iṣoro naa gẹgẹ bo ṣe
jẹ awọn ọdọ nikan lo lesọ nnkan to n ṣẹlẹ.
Nigba to n ke si gbogbo awọn
Ọba ilẹ Yoruba patapata, Aarẹ ẹgbẹ YCYW sọ pe ko too to asiko ti ipade to nii
ṣe pẹlu ọrọ aje ati eto aabo ilẹ Yoruba (A Southwest
Economic Revitalization and Security Summit) too waye ninu oṣu kẹfa ọdun,
ki wọn ti tete gbe igbesẹ lati wa ọna abayọ ti yoo jẹ ki alaafia jọba.
O ke si gbogbo awọn Ọba ilẹ
Yoruba patapata lati ori Ọọni Ile Ifẹ, Ọba Babatunde Ẹnitan Ogunwusi; Alaafin
Ọyọ, Ọba Ọlayiwọla Atanda Adeyẹmi 111; Ọba Riliwan Akiolu, Ọba Elekoo; Ọba Aholu Mẹnu Toyi 1, Akran tiluu Badagry; Ọba Frederick Akinruntan, Olugbo ti Ugbo; Ọba Adewale Akanbi Teluwo, Oluwo tiluu Iwo; Ọba Sikiru Adetọna, Awujale tilẹ Ijẹbu atawọn min in.
Awọn Agbaagba to ku bii Aarẹ
Ọna Kakanfọ, Ọtunba Gani Adams awtwọn ẹgbẹ bii: Agbẹkọya,
Afẹnifẹre,
ARG, OPC, OLM, Yoruba Kọya,
Yoruba Assembly, YSG, VOR, awọn ọdọ atawọn olori ẹgbẹ awọn akẹkọọ.
Bakan naa lo tun pe awọn
Ọjọgbọn, Ọlọlajulọ, Agbaagba, Alaṣẹ ati Apaṣẹ Oloṣelu pe ki wọndakun gbaruku ti
eto to n bọ lọna naa lati wa ọna abayọ si eto ọrọ aje orileede Naijiria, paapaa
ilẹ Yoruba.
No comments:
Post a Comment