ỌWỌ ỌLỌPAA TẸ KABIYESI TO N JALE, ILU-ONILU LO TI N JALE - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Tuesday, May 21, 2019

ỌWỌ ỌLỌPAA TẸ KABIYESI TO N JALE, ILU-ONILU LO TI N JALE

"Ko gbọdọ pada siluu mọ, ẹ jẹ ko ku sẹwọn" lọrọ to n tẹnu awọn araalu Ipene nijọba ibilẹ Baise, ipinlẹ Cross Rivers n sọ, nigba tọwọ ọlọpaa tẹ kabiyesi wọn, Ọba Chief Paulinus Ogbor, pẹlu ọlọpaa kan to ti fẹyinti, Onugh lori ẹsun pe wọn ji ẹrọ amunawa (transformer) ti ko din ni mẹta gbe.

Agbẹnusọ fun ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ẹbọnyi, Loveth Odah lo fidi iṣẹlẹ naa mulẹ laipẹ yi pe loootọ ni Kabiyesi ati ọlọpaa to ti fẹyinti naa ti wa lahamọ awọn.


Ohun ta a gbọ ni pe awọn 13 Brigade ti ileeṣẹ ologun nipinlẹ Calabar, ti wọn paala ni Unwana ijọba ibilẹ Afikpo North, Ẹbọnyi lo rọwọ to Kabiyesi naa lọjọ Fraide ọsẹ tokọja, ti wọn si lọọ fa a le awọn ọlọpaa lọwọ.

AWIKONKO gbọ pe awọn ẹrọ amunawa naa to jẹ ti awọn agbegbe Umuolo, Etana, Ubum, Edu, Ibini, Afono, Urugbam, Ipene ati Egbor to wa nijọba ibilẹ Biase, ipinlẹ Cross River.

A gbọ pe ọjọ Fraide lawọn ọdaran naa lọ lati lọọ ko awọn ẹrọ amunawa naa pe awọn fẹẹ ko wọn lọ fawọn to ni wọn, ibi ti wọn ti n lọ sibi ti wọn ti fẹẹ ta wọn la gbọ pe aṣiri wọn ti tu sawọn ologun naa lọwọ ni nnkan bi aago mọkanla aabọ alẹ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI