NITORI IPADE ỌTẸ: GOMINA AJIMỌBI FARIGA, O LOUN KO NI GBE IJỌBA FUN MAKINDE L'ỌSẸ TO M BỌ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Saturday, May 25, 2019

NITORI IPADE ỌTẸ: GOMINA AJIMỌBI FARIGA, O LOUN KO NI GBE IJỌBA FUN MAKINDE L'ỌSẸ TO M BỌ

Pupọ ninu awọn to gb nnkan ti Gomina Abiọla Ajimọbi tipinlẹ Ọyọ sọ lalẹ ana, lẹyin to de lati ilu Abuja, nibi to ti lọọ ṣabẹwo sii ni wọn n bu ẹnu atẹ luu, ti wọn si n sọ pe ko yẹ ko gbe iru igbesẹ bẹẹ.

Bo tilẹ jẹ pe awuyewuye kan to lu si AWIKONKO lọwọ jẹ ko ye wa pe awọn kan ti n ṣe ipade lati doju ti Gomina Ajimọbi nibi eto ipaarọ agbara, eyi to fẹẹ waye lọjọ Wẹside ọsẹ to nbọ, ti wọn si lọrọ naa ti lu si Gomina leti.

A gbọ pe awọn kan ti ko tii sẹni to mọ baba isalẹ wọn dasiko ta a fi kọ iroyin yi tan ti pari igbesẹ lati konọ iya fun Gomina Ajimọbi latari awọn iwa atawọn ọrọ buruku ti wọn loo ti sọ, ati bi wọn loo ṣe ba iinlẹ naa jẹ, paapaa bi ko tun ṣe jẹ kẹgbẹ oṣelu APC rọwọ mu ninu idibo to kọja.

AWIKONKO gbọ pe, bi ọrọ naa ṣe lu si Gomina Abiọla Ajimọbi lọwọ laipẹ yi, lo mu ko tẹkọ leti gba iluu Abuja lọ lọdọ Aarẹ Buhari, to si lọọ ṣalaye awọn nnkan to n ṣẹlẹ, ati pe ko ma ṣe binu soun, iyẹn to ba gbọ pe oun ko ni yọju sibi eto ipaarọ agbara lọjọ kọkandinlọgbọn oṣu yi.

Ohun ta a gbọ ni pe bo tilẹ jẹ pe Aarẹ Buhari ko kọkọ fẹẹ fọwọ sii, ṣugbọn lẹyin ọpọlọpọ ẹbẹ la gbọ pe Aarẹ Buhari sọ pe ko ṣe nnkan to ba ti ọkan ẹ wa, tori pe oun ko fẹ kawọn eeyan tun ri toun sọ.

Bi Gomina Ajimọbi ṣe de pada, oun to bawọn oniroyin sọ ni pe ẹdun ọkan lo jẹ foun pe oun ko nii si nile lasiko ipaarọ agbara naa, tori pe oun n lọ si Umurah lati lọọ gbadura, koun si dupẹ lọwọ Ọlọrun fun aṣeyọri gẹgẹ bi Gomina.

O ni boun yoo ba fi pada de titi ipari ọsẹ naa, ijọba tuntun ni yoo ti wa lori ipo.

Ninu ọrọ ẹ, Gomina Ajimọbi sọ pe "Nnkan to n jẹ ibanujẹ fun mi ni pe mi o ri awọn nnkan to wun mi lọkan lati ṣe ṣe. Iba jẹ pe ọrọ mi ye awọn eeyan wa ni, ki wọn si ni suuru, ṣugbọn o ṣeni laanu pe awọn eeyan wa ko fẹ ayipada rere.

"Mo fẹẹ dupẹ lọwọ Aarẹ Muhammadu Buhari fun ifọwọsowọpọ ẹ lasiko ọgbẹ-ilẹ lati ṣiṣẹ, lati san owo oṣu ati lati mu eto ọrọ aje wa si irọrun. Bi mo n sẹ sọrọ yi, pupọ ninu awọn ipinlẹ kaakiri, to fi mọ ipinlẹ Ọyọ ni ko jẹ gbese owo oṣu kankan.

"Idi ti mo fi lọọ ki Aarẹ Buhari ni lati dupẹ lọwọ, ati pe ka too ri ọjọ meji si asiko yi, mo fẹẹ lọ si Umurah, ti n ba si maa pada de, ijọba tuntun yoo ti wa ni ọfiisi gẹgẹ bi Gomina. Mo fẹẹ lọ si Umura lati lọọ dupẹ lọwọ Ọlọrun."

 Ohun tawọn eeyan n sọ ni pe ko yẹ ko jẹ iru asiko yi gan an lo yẹ ki Gomina Ajimọbi sọ pe oun fẹẹ rin irin ajo, ati pe latari itiju to ṣee ṣe ko ba pade nibi eto naa lo mu ko pinu lati salọ fungba diẹ. Bẹẹ lawọn kan sọ pe kani Ẹgbẹ oṣelu APC lo jawe olubori nibi idibo Gomina ni, Gomina Ajimọbi ko nii pinu lati gbe igbesẹ naa.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI