IKUNLẸ ABIYAMỌ O: EEFIN JẸNẸRETỌ PA ẸGBỌN ATI ABURO RẸ SINU ṢỌỌBU - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Thursday, May 23, 2019

IKUNLẸ ABIYAMỌ O: EEFIN JẸNẸRETỌ PA ẸGBỌN ATI ABURO RẸ SINU ṢỌỌBU

Bawọn kan ṣe n sọ pe ọrọ naa kii ṣoju lasan, o lọwọ aye ninu, bẹẹ lawọn kan n sọ pe eefin jẹnẹretọ ni, tawọn min in si n bẹbẹ pe kawọn ọlọpaa tubọ ṣe iwadii kikun lori iku to pa tẹgbọn taburo kan sinu ṣọọbu l'Ọjọta, niluu Eko.

Ọjọ Tuside to kọja yi la gbọ pe iṣẹlẹ kayeefi naa waye, nigba ti wọn ni tẹgbọn taburo naa, Michael ọmọdun mọkalelogun ati aburo ẹ, Paul toun jẹ ọmọdun mọkandinlogun ku sinu ṣọọbu.

Bo tilẹ jẹ pe oun tawọn eeyan n sọ tẹlẹ ni pe ṣe lawọn mejeeji gbe majele jẹ, ṣugbọn ti iwadii pada fidi ẹ mulẹ fawọn ọlọpaa pe eefin jẹnẹretọ pa wọn mọnu ṣọọbu naa.

AWIKONKO gbọ pe Michael ati Paul ni wọn maa n kọkọ ṣi ṣọọbu lagbegbe naa, tori pe inu ṣọọbu naa ni wọn n sun. Ṣugbọn iyalẹnu lo jẹ nigba ti wọn ko ri awọn mejeeji ki wọn tete ṣi ṣọọbu laarọ ọjọ naa.

Eyi gan an ni wọn lo n fu awọn eeyan ti wọn jọ wa nitosi lara, to mu ki wọn bẹrẹ sii pe foonu wọn. Nigba ti wọn maa gbọ, inu ṣọọbu ni wọn ti n gbọ ohun foonu wọn, to n dun.

Eyi gan an la gbọ pe o mu kawọn eeyan naa pariwo sita, ti wọn si fibinu ja ṣọọbu naa lati wo nnkan to n ṣẹlẹ, nigba ti wọn maa ri awọn mejeeji nibi ti wọn sun si,oku wọn ni wọn ba.

Lẹsẹkẹsẹ lawọn eeyan ti ranṣẹ pe awọn ọlọpaa lati wa a wo nnkan to n ṣẹlẹ.

Ohun tawọn kan n sọ fawọn ọlọpaa ni pe ki wọn tubọ ṣe iwadii kikun lati mọ nnkan to pa wọn, tori pe wọn ko ṣẹṣẹ maa tan jẹnẹretọ naa, to si jẹ pe gbogbo ile lo n loo.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI