NITORI ẸSUN JIBITI, WỌN JU ỌMỌ YAHOO MẸRIN SẸWỌN L'ABẸOKUTA - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Thursday, May 23, 2019

NITORI ẸSUN JIBITI, WỌN JU ỌMỌ YAHOO MẸRIN SẸWỌN L'ABẸOKUTA

Lọjọ Wẹside ana nile ẹjọ giga tijọba apapọ ran awọn mẹrin kan, ti wọn ni wọn ko niṣẹ meji ju jibiti ori ayelujara lọ, iyẹn Yahoo-Yahoo sẹwọn pe ki wọn lọọ gbatẹgun alaafia fungba diẹ, bẹẹ lo tun paṣẹ pe ki wọn da gbogbo owo ti wọn fi jibiti gba pada lẹsẹkẹsẹ.

AWIKONKO gbọ pe awọn EFCC lati ilu Ibadan ni wọn wa a ko awọn ọmọ Yahoo naa, ti wọn si foju wọn bale ẹjọ akọkọ ati ikeji (Fedral High Court 1 and 2).

Awọn mẹrẹẹrin naa ni Ọlatunji Samọd Ọladimeji (a.k.a Theresa), Stephen Ayọọla Ogunmẹfun (a.k.a Michael Schwarz), Adekanmbi Abdulazeez ati Tẹlla Adefẹmi Ibrahim, ti wọn lawọn jẹbi awọn ẹsun ti wọn fi kan wọ. 

Lara awọn ẹsun ti wọn fi kan wọn ni pe wọn n fi awọn fọto onihoho ranṣẹ, ti wọn si tun n lo alupayida fawọn ti wọn n lu ni jibiti, eyi ti wọn loo tako ofin ọdaran ayelujara tọdun 2015, to si ni ijiya.

A gbọ pe nigba to n gbe idajọ kalẹ, Onidajọ Ibrahim Watilat paṣẹ pe ki Ogunmẹfun ati Abdulazeez lọọ ṣẹwọn oṣu marun-marun pere, ki wọn, ati pe ki Abdulazeez da igba owo dọla ($200) to fi jibiti gba pada fẹni to nii, ki Ogunmẹfun si da ẹgbẹrin owo Euro (€800) ati dọla marundinlọgọrin ($75) to fi jibiti gba.

O paṣẹ pe ki wọn san owo naa sinu apo owo ijọba apapọ orileede Niajiria, lati le daa pada fun wọ, bẹẹ lo tun ni gbogbo awọn dukia patapata ti wọn gba lọwọ wọn ti di ti ijọba.

Onidajọ Muhammed Abubarkar ju Tẹlla ati Ọlatunji sẹwọn oṣu mẹta-mẹta, to si ni ki Tẹlla gbagbe miliọnu kan naira, mọto, Honda Accord, HP Laptop, IPhone 8 ati foonu Samsung X9 ti gba lọwọ ẹ.

Bẹẹ lo tun sọ pe ki Ọlatunji da ẹẹdẹgbẹrin owo dọla ($700) ati aadọta Euro (£50), ati pe ko gbagbe Infinix Note 4, Dell Laptop ati HP Laptop ti wọn gba lọwọ oun naa patapata.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI