WỌN TI RỌ KABIYESI TO N ṢẸGBẸ OKUNKUN L'OYE O - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Tuesday, May 21, 2019

WỌN TI RỌ KABIYESI TO N ṢẸGBẸ OKUNKUN L'OYE O

Kayeefi lọrọ Kabiyesi tijọba ipinlẹ Rivers rọ loye laipẹ yi ṣi n jẹ fun ọpọ awọn eeyan, latari ẹsun ti wọn fi kan ọba naa, Alayeluwa, Mọnday Frank Noryaa pe o n ṣẹgbẹ okunkun, o si tun n jẹ baba isalẹ fawọn igara ọlọṣa.

Ninu atẹjade ti amugbalẹgbẹ Gomina ipinlẹ naa lori ọrọ iroyin ayelujara, Simeon
Nwakaudu lo ti kede yiyọ ti wọn yọ ọba naa to jẹ Gbenemene tiluu Baabe, nijọba ibile Khana.

AWIKONKO gbọ pe lẹsẹkẹsẹ ni wọn ti gba iwe aṣẹ lọwọ, ti wọn tun gba de lori ẹ pe awọn ko le fi ọdaran jẹ olori laarin ilu.

A gbọ pe gbogbo wahala awọn ọmọ ẹgbẹ lagbegbe naa, ko ṣẹyin ọba ti wọn rọ l'oye yi, nitori pe gbogbo bawọn eleto aabo ṣe n gbiyanju lati jẹ ki wahala naa tan, ni wọn sọ pe Kabiyesi yi ko gba fun wọn.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI