IYA NLA LAWỌN ADIGUNJALE MEJI YI BA PADE - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Friday, May 10, 2019

IYA NLA LAWỌN ADIGUNJALE MEJI YI BA PADE

Bi wọn ba n beere lọwọ awọn ọrẹ meji ti ẹ n wo yi pe ọjọ wo ni wọn ko le gbagbe nigbesi aye wọn lọjọ iwaju, ko si ọjọ meji ti wọn yoo sọ ju ọjọ kẹsan an oṣu karun un ọdun 2019, ko da a, wọn a tun sọ pe ọjọ buruku eṣu gbomimu ni.

Awọn gendekunrin meji yi la gbọ pe wọn niṣẹ meji ju ki wọn maa fi ibọn ilewọ gba foonu lọ, bẹẹ ni wọn tun n fi lọọ fọ ile onile.

Ipinlẹ Bayelsa lọwọ ti tẹ wọn lẹyin ti wọn yọ ibọn si gendebinrin kan ti wọn pe orukọ ẹ ni Betty, ti wọn si gba foonu lọwọ ẹ.

Lẹyin ti wọn gba foonu naa tan, lọmọbinrin naa pariwo 'ole' tẹle wọn lẹyin ko too di pe awọn eeyan sare tẹle wọn, tọwọ palaba wọn si segi.
Diẹ lo ku ki wọn dana sun wọn, awọn ẹlẹyinju aanu lo gba wọn silẹ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI