WỌN NI ILEEWE TO WO PA AKẸKỌỌ L’ONDO KII ṢOJU LASAN O - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Saturday, May 25, 2019

WỌN NI ILEEWE TO WO PA AKẸKỌỌ L’ONDO KII ṢOJU LASAN O

Ṣe lọrọ di boolọ o yago lọna lana tii ṣe Fraide nigba ti ogiri ileewe girama Saint Andrew to wa nijọba ibilẹ Ondo West dee de wo lojiji, to si pa akẹkọọ kan ti wọn pe orukọ ẹ ni Esther Akinrinọla danu lẹsẹkẹsẹ.

Ni nnkan bi aago mejila ọsan la gbọ pe ogiri kilaasi kan nileewe naa ṣa deede ya lulẹ lasiko tawọn akẹkọọ gba idanilẹkọọ wọn lọwọ.

Ohun ta a gbọ ni pe wọn ti pa kilaasi naa ti lọjọ to ti pẹ latari bi wọn ṣe lo ti n mu ifura dani pe ko igbakigba lo le wo lulẹ, ko si ma baa paayan tabi ṣe eeyan leṣe lo jẹ ki wọn paa ti.

A gbọ pe Esther ti wọn lọmọdun mẹrinla, to si wa nipele ẹkọ kẹta (JSS3) jade lọọ ṣẹyọọ (urinate) nitosi kilaasi naa, asiko to n pada bọ la gbọ pe ogiri naa wo lulẹ, to si wo lee lori.

Awọn tiṣẹlẹ naa ṣoju wọn la gbọ pe wọn ke gbajare, ti gbogbo inu ọgba ileewe naa si fẹẹ le daru. Loju ẹsẹ la gbọ pe wọn gbe Esther digba-digba lọ si ọsibitu ijọba tawọn akẹkọọ, iyẹn Ondo State University of Medical Sciences Teaching Hospital fun itọju, oju ọnọ lo ti dake.

Agbẹnusọ fawọn ọlọpaa ipinlẹ Ondo, Ọgbẹni Fẹmi Joseph fidi iṣẹlẹ naa mulẹ, o si bu ẹnu atẹ lu bi wọn ko ṣe tete gbe igbesẹ lori kilaasi naa lati woo lulẹ, ko too wo paayan.

Ohun tawọn to gbọ siṣẹlẹ naa n sọ pe ni pe kii ṣoju lasan, tori pe o ṣee ṣe ko jẹ pe asiko ọmọ naa lo to, to si jẹ pe sababi lo n wa, bẹẹ lawọn kan n gbadura pe ki Ọlọrun ma jẹ ka ku iku oro, tawọn min si n gbadura pe ka ma ri iku ọmọ.

Bákan láwọn min in sọ pe afọwọfa ijoba at'awọn alaṣẹ ileewe naa ni.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI