O MA ṢE O: BARCELONA RU IGI OYIN NILE LIVERPOOL, LAWỌN OLOLUFẸ BARCA BA BU SẸKUN - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Tuesday, May 7, 2019

O MA ṢE O: BARCELONA RU IGI OYIN NILE LIVERPOOL, LAWỌN OLOLUFẸ BARCA BA BU SẸKUN

Gbogbo awọn ololufẹ ẹgbẹ agbabọọlu Barcelona ni ko le tete gbagbe iya ajẹkudorogbo ti ẹgbẹ agbabọọlu Liverpool gbe le wọn lọwọ lalẹ oni ni papa iṣere Anfield.

Idije yi lo fun ẹgbẹ agbabọọlu Liverpool lanfaani lati kopa ninu aṣekagba idije Champions League pẹlu bi wọn ṣe doju Barcelona bolẹ pẹlu aami ayo mẹrin si oodo.

Goolu mẹta ni Barcelona fi n lewaju lati abala kini ifẹsẹwọnsẹ wọn lọsẹ to kọja amọ Liverpool da goolu na pada ti wọn si tẹsiwaju lati bori Barcelona pẹlu ami ayo mẹrin si mẹta.

Divock Origi lo kọkọ jẹ goolu ni iṣẹju keje ifẹsẹwọnsẹ naa ti o si fi goolu mi da Barcelona loro ni iṣẹju kọkandinlogọrin ti o fi jẹ goolu mẹrin si odo.

Bi ala ni ọrọ naa ri loju ọpọ alatilẹyin ẹgbẹ Liverpool nitori pe awọn to jẹ eekan ẹgbẹ wọn meji Mohammed Salah ati Firminho ko kopa ninu ifẹsẹwọnsẹ naa.

Amọ aisini ori papa wọn ko fi Liverpool rara.

Ninu idije Champions League, iru itu bayi ṣọwọn ti awọn eeyan ṣi n kan sara si Liverpool.

Tottenham ati Ajax ni yoo koju ninu ifẹsẹwọnsẹ keji lati mọ ẹni ti yoo pade Liverpool ninu aṣekagba idije naa ti yoo waye ni Madrid.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI