WỌN NI FADEYI OLORO DAKU FUN WAKATI MẸRIN, IRANLỌWỌ OWO LO NILO BAYII - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Sunday, May 5, 2019

WỌN NI FADEYI OLORO DAKU FUN WAKATI MẸRIN, IRANLỌWỌ OWO LO NILO BAYII

Bo tilẹ jẹ pe lati bi ojo meloo kan sẹyin lawọn kan ti n gbe iroyin naa kaakiri pe gbajugbaja oṣere tiata to fẹran lati maa ṣere oloogun, Ọgbẹni Ojo Arowoṣafẹ, ẹni tọpọ awọn eeyan mọ si Fadeyi Oloro ti papoda, to mu kawọn kan maa beere pe ṣe loootọ ni.

Bẹ o ba gbagbe, laipẹ la gbe iroyin kan to da bi ibeere jade sita, latari bi gbogbo akitiyan lati bawọn to sunmọ Fadeyi Oloro sọrọ ṣe ja si pabo. Ibeere naa la pe ni: Ṣe loootọ ni Fadeyi Oloro ti ku.

Ni bayii, AWIKONKO ti pada gbọ pe lootọ ni ọkunrin naa daku, ṣugbọn fun wakati mẹrin pere ni, to si ti pada ji saye. Laarin asiko ti Fadeyi Oloro fi daku yi, lawọn eeyan fi n pokiki iku ẹ kaakiri pe o ti ku, ti wọn ko si pada ṣewadi nnkan to ṣẹlẹ lẹyin ẹ.

Awọn to firoyin naa to AWIKONKO leti ti pada jẹ ko ye wa pe aisan kidinrin (Kidney Problem) ni wọn lo n da ọkunrin naa laamu, to si nilo obitibiti owo lati fi toju ara rẹ.

Ọsẹ to kọja yi la gbọ pe Fadeyi Oloro kuro nileewosan to ti n gba itọju.

Fawọn to ba nifẹ si lati ran Fadeyi Oloro lọwọ nipa ọrọ owo, aaye ṣi silẹ, ẹ ma jẹ koun naa kuro loke eepe lasiko yi, nitori tawọn ololufẹ ẹ ṣi n fẹ ko pada sidi iṣẹ tiata to sọ ọ di olokiki.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI