AFCON 2019: TARIBO JU BỌMBU ỌRỌ SI SUPER EAGLES - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Thursday, June 6, 2019

AFCON 2019: TARIBO JU BỌMBU ỌRỌ SI SUPER EAGLES

Ọkan pataki lara awọn agbabọọlu orilẹ-ede Naijiria tẹlẹ, Taribo West ti ju bọmbu ọrọ si ikọ Super Eagles pe oun ko le ko owo oun le ẹgbẹ agbabọọlu naa lori pe wọn yoo gba ife ẹyẹ idije bọọlu ilẹ adulawọ, iyẹn African Cup of Nations, eyi to fẹẹ waye lorilẹ-ede Egypt lọdun yi.

Taribo, to jẹ ọkan pataki lara awọn agbabọọlu Inter Milan ati Auxerre tẹlẹ lo sọrọ naa nibi ifọrọwerọ to ṣe pẹlu oniroyin kan laipẹ yi, to si ni latari agbeyẹwo toun ṣe nipa awọn to n lọ sibi idije, o maa ṣoro foun lati ta tẹtẹ pe Super Eagles yoo bori.

Super Eagles to wa ni ẹgbẹ keji (Group B) ninu idije naa ni yoo koju ikọ ẹgbẹ agbabọọlu Madagascar, Burundi ati Guinea. Burundi ni ikọ Super Eagles yoo fi ṣide niluu Alexandria lọjọ kejilelgoun oṣu yi.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI