ARẸTA (ABẸOKUTA), ILUU TI WỌN KO TI NI ILE ẸKỌ FUN ỌGỌRUN ỌDUN - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Saturday, June 29, 2019

ARẸTA (ABẸOKUTA), ILUU TI WỌN KO TI NI ILE ẸKỌ FUN ỌGỌRUN ỌDUN

Bi wọn ba n sọ nipa awọn nnkan to n mu ayipada rere de ba ijọba ibilẹ, ipinlẹ, paapaa orilẹ-ede kan, ko si nnkan meji bi ko ṣe ẹkọ. Ẹkọ ṣe pataki, o ṣe koko, ti ko si ṣe e fọwọ rọ ti sẹyin ninu awọn nnkan to n mu idagbasoke ba iluu.

Ko si orilẹ-ede kan lagbaye yi ti wọn ti n fi ọrọ ẹkọ ṣere, bi iru orilẹ-ede bẹẹ ba si wa, a jẹ pe iru orilẹ-ede bẹẹ ti wa loko iparun, tori pe oni okunkun biribiri ni wọn yoo ti maa lo igbesi aye wọn.

Pupọ ninu awọn eeyan, ajọ tabi ẹgbẹ ti wọn n ṣe iranlọwọ fawọn eeyan nipa ọrọ ẹkọ ni wọn maa n jẹri pe awọn ko kabamọ nnkan tawọn n ṣe nitori pe ọjọ iwaju awọn lawọn n tun ṣe.

Kii ṣe ahesọ, awọn ilu kan ṣi wa lorilẹ-ede Naijiria, bi a yọ tawọn agbegbe kan lapa oke ọya ti wọn ko fi bẹẹ kundun eto ẹkọ, to jẹ pe wọn ti ni ile ẹkọ depodepo pe wọn yoo jẹ anfaani ijọba awaarawa, tijọba naa ko si ṣetan lati wa ọna abayọ sawọn agbegbe naa, paapaa nilẹ Yoruba.

Ibi tawọn akẹkọọ ti n gba idanilẹkọọ tẹlẹ
Eyi lo mu ki awọn adari ajọ alaanu kan ti wọn n ṣe iranlọwọ fawọn araalu jakejado orilẹ-ede Naijiria ati kaakiri agbaye pẹluu, iyẹn ajọ naa ti wọn pe ni Destiny Support Africa Foundation of Nigeria gba ilu kan ti wọn n pe ni Arẹta, to wa nijọba ibilẹ Ọdeda, ipinlẹ Ogun lati lọọ wo iranlọwọ ti wọn yoo ṣe fun idagbasoke agbegbe naa.

Loootọ, ilu naa ti wa lati bi ọgọrun ọdun sẹyin, to si jẹ pe awọn naa le fọwọ sọya pe awọn ni ile ẹkọ alakọbẹrẹ, ṣugbọn to jẹ pe abẹ igi ọsan lawọn ogowẹẹrẹ wọn ti n gba ẹkọ nibẹ. Latigba ti wọn ti sọ agbegbe Arẹta nitosi Alabata lorukọ, lo ti jẹ pe ko si ogiri kan ti wọn le sọ pe ile ẹkọ re e nibẹ, bẹẹ awọn oloṣelu maa n lọ sawọn agbegbe naa lọọ ṣe ipolongo to ba ti to asiko idibo lati gba ijọba tuntun.

Ile ẹkọ tuntun naa
Ajọ ti a n sọ yi ni Wolii, Arabinrin Ayọka Ọlabisi to jẹ ọmọ bibi ipinlẹ Ondo da silẹ lọdun diẹ sẹyin, to si jẹ pe pupọo awọn eeyan ni wọn dupẹ lọwọ oludasilẹ naam to tun fi ile alawọ funfun ṣebugbe bayii.

Gẹgẹ bi a ṣe gbọ, ọdun to kọja ni Arabinrin Ayọka Ọlabisi lọọ ṣi awọn iṣẹ akanṣe meloo kan to fi ṣe iranlọwọ fawọn eeyan agbegbe kan, nibẹ lo ti gbọ nipa iroyin agbegbe ti wọn n pe ni Arẹta yi, kayeefi ni wọn loo jẹ fun un nigba to gbọ pe abẹ igi lawọn ogowẹrẹ ti n gba idanilẹkọọ.
Lasiko ti wọn n ṣii

Eyi ni wọn loo muu lọ sibẹ lati lọọ ṣewadii, to si ri i pe loootọ ni ile ẹkọ kan wa ti wọn n gba idanilẹkọọ labẹ igi, ati pe Community Primary School lorukọ rẹ. Pẹlu itara lobinrin naa fi gbe owo kalẹ lati kọ ile ẹkọ sibẹ, nigba to rii pe ijọba gan an ko mọ pe iru nnkan bẹẹ wa nibi ti wọn ti n gba owo ori lọwọ awọn olugbe agbegbe naa.

Ṣe ni idunnu ṣubu lu ayọ awọn araalu laipẹ yi nigba ti wọn ṣi ile ẹkọ naa fun lilo awọn akẹkọọ, ti wọn jẹ ogowẹẹrẹ, ti gbogbo ili si peju sibẹ pe awọn ti bẹrẹ sii jẹ anfaani ti ko wọpọ.

Nibi ti wọn ti ṣi ile ẹkọ tuntun naa ni wọn tun ti lo anfaani ẹ lati fawọn akẹkọọ ni aṣọ tuntun, iwe, takada atawọn nnkan ti yoo mu ikẹkọọ wọn rọrun, ko da a, ti Ọba wọn, Olu tiluu Alabata, Ọba Abdulwaheed Ṣanusi gan an ko gbẹyin nibẹ, toun naa si ṣe ileri pe gbogbo ipa ati agbara oun loun yoo fi rii pe iṣẹ ko dawọ duro ni ẹka eto ẹkọ.

Nigba to n sọrọ, Rẹfurẹndi, Arabinrin Ayọka Ọlabisi jẹ ko di mimọ pe ko si nnkan meji to jẹ koun mu ọrọ ẹkọ lokunkundun, bi ko ṣe pe oun ko lanfaani lati tete ri ẹni ti yoo ran oun lọwọ lati lọ sile iwe, latyari agbara ti ko si lọwọ awọn obi oun.

O ni idi pataki re e toun fi da ajọ naa silẹ, toun si tun n ri iranlọwọ gba lati ọdọ awọn to ni iru afojusun toun ni. Ojiṣẹ Ọlọrun naa gba ijọba lamọnran pe ki wọn rii daju pe iru awọn agbegbe bayii ni wọn n ṣe iranlọwọ fun, kawọn olugbe le jẹ mudun-mudun ijọba awaarawa.

Nigba toun naa n sọrọ, Alaaji Bọla Lawal, to ṣoju Gomina ipinlẹ sọ pe pẹluu boun ṣe ti figba kan ri jẹ alaga ijọba ibilẹ Ọdẹda ti Arẹta wa labẹ, oun ko figba kan mọ ri pe iru nnkan bayii n ṣẹlẹ nibẹ, ati pe toun ba ti ẹ mọ, ko si nnkan toun fẹ ẹ ṣe, tori pe ijọba ti to kuro nibẹ ti yọwọ ijọba ibilẹ lawo nipa ọrọ idagbasoke iluu.

O wa a ṣeleri pe ijọba Dapọ Abiọdun, pẹluu bo ṣe n fojoojumọ tẹnumọ eto ẹkọ, o ṣetan lati mu ọrọ eto ẹkọ lokunkun dun, ko da a, ti yoo jẹ nnkan akọkọ ti yoo jẹ ijọba logun. Bẹẹ lo sọ pe ijọba Dapọ Abiọdun ṣetan lati da ogo eto ẹkọ to ti sọnu tipẹ pada, ti yoo si maa figagbaga pẹluu ẹkọ lagbaye. 

Ninu ọrọ ti Olu tiluu Alabata, Ọba Abdulwaheed Ṣanusi dupẹ lọwọ Iranṣẹ-Ọlọrun nni, Arabinrin Ayọka fun ipinu ẹ lati maa ran awọn alaini lọwọ, to si ṣeleri pe oun naa yoo tubọ tẹramọ iranlọwọ toun n ṣe fawọn ju ti tẹlẹ lọ.

O wa a gba awọn akẹkọọ lamọnran pe ki wọn ma ṣe fi ayọ ayọju ba awọn dukia ile iwe tuntun naa jẹ, to si tun gbawọn olukọ lamọnran pẹ ki wọn tẹramọ kikọ awọn akẹkọọ lẹkọ to ye kooro.

IMG_ORG_1561107464406

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI