O TUN ṢẸLẸ O, IYAALE ILE, ỌMỌ OGUN ỌDUN TI GUN ỌKỌ RẸ PA O - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Saturday, June 29, 2019

O TUN ṢẸLẸ O, IYAALE ILE, ỌMỌ OGUN ỌDUN TI GUN ỌKỌ RẸ PA O

Laarọ onii, Abamẹta, ṣe ni ẹsẹ girigiri ko sin lagbegbe Nsigbe to wa nijọba ibilẹ Anambra East nibi ti iyaale ile ẹni ogun ọdun kan, Makoduchukwu Ndubisi ti gun ọkọ rẹ, John Bosko Ngu toun jẹ ọmọdun marundinlogoji pa, latari ọrọ ti wọn ni ko to nnkan to ṣẹlẹ laarin wọn.

Ojule ogun, adugbo Donking ni wọn sọ pe tọkọ-tiyawo naa n gbe, nibẹ niṣẹlẹ buruku naa ti waye ni nnkan bi aago mẹjọ aarọ. Ohun ta a gbọ ni pe, ṣadede lawọn araale gbọ ariwo, ti wọn lọ sibẹ lati yọju wo nnkan to n ṣẹlẹ, nigba ti wọn maa dẹbẹ, John ni wọn ba nilẹ, to n japoro.

Gẹgẹ awọn to firoyin naa to wa leti ṣe sọ, wọn lawọn tọkọ-tiyawo naa ko ṣẹṣẹ maa ni gbọnmisi-omioto laarin ara wọn, to si jẹ pe oriṣiriṣi ẹsun ni wọn fi maa n kan ara wọ, ko da a, ta a gbọ pe awọn onile gan an ti fun wọn niwe pe ki wọn jade, ṣugbọn ti wọn ko gbọ.

A gbọ pe wahala tawọn mejeeji n fa ladugbo poju agbara awọn eeyan lo, ti wọn lawọn eeyan si ti kilọ fun iyaale ile naa pe ko ye e ba ọkọ rẹ ja, ṣugbọn ti wọn lo maa n sọ pe ko si nnkan to wọn nibẹ.

Wọn ni nigba tawọn araale rii pe iyaale ile naa ri John nibi to ti n japoro, ni wọn ti duu titi lati doola ẹmi ẹ, ṣugbọn ti akukọ pada kọ lẹyin ọmọkunrin rẹ. Eyi ni wọn lo mu awọn eeyan ranṣẹ sawọn ọlọpaa lati wa a woran.

Nigba tawọn ọlọpaa si maa debẹ lootọ, oku baale ile yi ni wọn ba, awọn la si gbọ pe wọn gbe oku naa lọ si mọṣuari fun ayewo siwaju sii. Loju ẹsẹ ni wọn ti mu Ndubisi lọ teṣan wọn lati lọọ fọrọ wa a lẹnu wo.

Alukoro ile-iṣẹ ọlọpaa ipinlẹ naa, Haruna Mohammed fidi ẹ mulẹ pe lootọ ni, ati pe iwadii ṣi n lọ lọwọ lati fọrọ wa iyaale ile naa lẹnu wo.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI