AYE O, WỌN JU AWỌN ỌMỌ YAHOO MẸFA SẸWỌN L'ABẸOKUTA - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Saturday, June 29, 2019

AYE O, WỌN JU AWỌN ỌMỌ YAHOO MẸFA SẸWỌN L'ABẸOKUTA

L'Ọjọbọ Tọside ijẹta yi ni ile ẹjọ giga apapọ kan to fikalẹ sagbegbe Oke-Mọsan niluu Abẹokuta ran awọn ọdọmọkunrin mẹfa kan lẹwọn pe ki wọn lọọ gbatẹgun alaafia fun igba diẹ.

 
Awọn ọdọmọkunrin naa ni: Ibrahim Adenẹkan, Akinniyi Bankọle Ojumu, Amọo Hammeed Ọlamide, Oshoala Abayọmi Ganiu, Ọpaaje Oluwatobi Isiah ati Ibukun Sunday. Wọn lawọn eeyan yi ko niṣẹ meji ju iṣẹ gbajuẹ ori ayelujara lọ, ati pe wọn ti lu ọpọ awọn eeyan ni jibiti pẹluu ọgbọn ayinike wọn.

 
Nigba taṣiri wọn maa tu, gẹgẹ bi a ṣe gbọ, wọn lawọn kan lo ta ile iṣẹ ajọ to n ri si iwa ibajẹ ati ṣiṣe owo kumọ-kumọ, iyẹn EFCC lati iluu Ibadan lolobo, ti wọn si wa a ko wọn. Wọn ni ayekaye tawọn eeyan naa n jẹ ni wọn loo tu aṣiri wọn, ati pe irin ẹsẹ wọn ko mọ laarin iluu Abẹokuta.

 
Fun bi oṣu meji gbako la gbọ pe awọn EFCC naa fi tọpinpin lati ṣewadii wọn, ko too di pe ọwọ pada tẹ wọn.

 
Nigba tawọn adajọ meji ọtọọtọ n gbe idajọ wọn kalẹ lori awọn ọdaran wọnyii, Onidajọ Ibrahim Watilat paṣẹ pe ki Amọo lọọ lo oṣu mẹta gbako lọgba ẹwọn pẹluu iṣẹ aṣe kara, bẹẹ ni Onidajọ Mohammẹd Abubakar naa paṣẹ pe ki Ibrahim, Akinniyi, Oshoala, Ọpaaje ati Ibukun naa lọọ fi ẹwọn oṣu mẹta pere gbara, lẹyin ti wọn ni gbogbo wọn gba pe loootọ lawọn jẹbi.

AWIKONKO gbọ pe gbogbo owo ati dukia ti wọn gba lọwọ wọn patapata ni wọn ko nii ri gba pada mọ, ati pe wọn yoo da gbogbo nnkan ti wọn lu jibiti ẹ pada fawọn ti wọn lu ni jibiti.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI