GOMINA ABIỌDUN GBE IGBIMỌ TI YOO TỌPINPIN IDASILẸ MAUSTECH ATI OGUN POLY DIDE - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Sunday, June 16, 2019

GOMINA ABIỌDUN GBE IGBIMỌ TI YOO TỌPINPIN IDASILẸ MAUSTECH ATI OGUN POLY DIDE

Bọsun Ọlaniyi, Abẹokuta

O ti n foju han bayii pe Gomina ipinlẹ Ogun, Ọmọba Dapọ Abiọdun ti ṣetan lati yanju wahala idasilẹ awọn ile-ẹkọ giga meji nni, Moshood Abiola University of Science and Technology to wa niluu Abẹokuta ati Ogun State Polytechnic toun wa niluu Ipokia, eyi ti gomina ana, Ibikunle Amosun ṣagbekalẹ ẹ.

Bẹ o ba gbagbe, latigba ti Gomina ana, Ibikunle Amosun ti loun da awọn ile-ẹkọ giga meji yi silẹ ni nnkan bii ọdun kan sẹyin, ni eto ẹkọ ti dẹnu kọlẹ patapata nipinlẹ Ogun, paapaa nile-ẹkọ giga gbogboniṣe ti MAPOLY.

Ni bayii, ninu atẹjade ti akọwe iroyin fun Gomina Dapọ Abiọdun, Ọgbẹni Kunle Ṣomọrin lo ti jẹ ko di mimọ pe ọrọ eto ẹkọ to jẹ ijọba yi logun lo mu ki wọn gbe igbimọ naa dide, lati tọpinpin idasilẹ awọn ile-ẹkọ wọnyii

O ni eto ẹkọ nile-ẹkọ yi ti dẹnu kọlẹ patapata, ti ko si jẹ kawọn akẹkọọ atawọn olukọni mọ nnkan ti wọn fẹẹ ṣe mọ, to si ba ilana ti wọn fi n ṣiṣẹ jẹ.

Gomina Abiọdun sọ pe ijọba to n fẹ ilọsiwaju ko le laju silẹ, ki nnkan maa fojoojumọ bajẹ, ati pe ilọsiwaju awọn eeyan lo gbọdọ jẹ ijọba lowo.

Igbimọ naa la gbọ pe Giwa ile-ẹkọ fasiti Tai Ṣolarin, Ọjọgbọ Ṣẹgun Awonusi ni alaga wọn, ti wọn yoo si maa wo bi iṣẹ ṣe n lọ si lawọn ile-ẹkọ meji naa, iyẹn Moshood Abiola University of Science and Technology, Abeokuta ati Ogun State Polytechnic, Ipokia.

Bẹẹ ni wọn yootun maa wo awọn amuyẹ ti wọn fi n da ile-ẹkọ giga silẹ, ati ojuṣe ijọba atawọn min in ni wọn yoo maa ṣagbeyẹwo ẹ.

Lara awọn ọmọ igbimọ naa ni: Alaaji Waheed Kadiri, ọga agba tẹlẹri ni MAPOLY; Ọjọgbọn Joseph Ọdẹmuyiwa, Aarẹ ẹgbẹ WEMAN (Workplace Educators & Managers Association of Nigeria); Dọkitọ Biọdun Oluṣẹyẹ to jẹ olukọ agba ni ile-ẹkọ gbogboniṣe ti Ilaro.

Awọn min in ni Agbẹjọro Abeeb Wale Ajayi; Ọgbẹni H.O. Ayọade, Aarẹ ẹgbẹ olukọni ni MAPOLY ati Dọkitọ Waheed  Ọlanloye, to jẹ oludari ẹka eto ẹkọ (Director Primary and tertiary education in the Ministry of Education, Science and Technology) toun yoo jẹ akọwe igbimọ naa.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI