ỌLỌRUN LỌWỌ SI IPADABỌ GOMINA FAYẸMI L'EKITI - BIṢỌỌBU ỌMỌTUNDE - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Sunday, June 16, 2019

ỌLỌRUN LỌWỌ SI IPADABỌ GOMINA FAYẸMI L'EKITI - BIṢỌỌBU ỌMỌTUNDE

Folukẹ Aduragbemi, Ọṣun
 
Biṣọọbu agba ti ijọ Aguda nipinlẹ Ekiti (Ekiti Anglican Diocese), Christopher Ọmọtunde ti sọ pe kii ṣe pe kii ṣe ibo awọn araalu lo gbe Gomina Kayọde Fayẹmi wọle ẹlẹẹkeji, bi ko ṣe pe ifẹ Ọlọrun nikan lo mu ki idibo to gbe e wọle naa lọ nirọwọ-irọsẹ, ati pe Ọlọrun lọwọ si bo ṣe pada wa lẹẹkeji lati mu ayipada rere ba ipinlẹ naa.
Biṣọọbu agba naa sọ pe ki ileri Ọlọrun atokewa le di mimu ṣẹ lo mu kawọn araalu dibo fun un lọpọ yanturu.
Oni ti i ṣe Sande ni ọrọ naa jade lasiko to n waasu nibi isin idupẹ ayẹyẹ ọjọ-ibi ọdun mẹrindinlọgọta ti iyawo Gomina Fayẹmi, Erelu Bisi Fayẹmi ṣe, nibẹ lo tun i jẹ ko di mimọ pe laarin asiko perete ti Gomina de ipo lo ti bẹrẹ sii mu awọn ohun meremere wọ ipinlẹ naa wa.

Lara awọn yo wa nibi isin idupẹ naa ni: Father Lawrence Adetọla; Gomina Kayọde Fayẹmi; Father Anthony Famuagun;Father Charles Atoki, atawọn min in.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI