Ẹ GBA MI LỌWỌ AWỌN ỌMỌ ẸGBẸ OṢELU APM TI WỌN FẸẸ BA TEMI JẸ O - GBENGA ẸSẸ MẸFA PARIWO SITA - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Monday, July 1, 2019

Ẹ GBA MI LỌWỌ AWỌN ỌMỌ ẸGBẸ OṢELU APM TI WỌN FẸẸ BA TEMI JẸ O - GBENGA ẸSẸ MẸFA PARIWO SITA

Ọkan pataki lara awọn to n du ipo alaga awọn to n wa Kẹkẹ Maruwa (Three Wheelers Owners and Rider Associaion, TWORA) nipinlẹ Ogun, Oloye Gbenga Ogunwale tọpọ awọn eeyan mọ si Ẹsẹ Mẹfa ti pariwo sita pe awọn ọta ti wọn ko fẹ ko koun de ipo naa ni wọn gbe iroyin ẹlẹjẹ sita nipa oun.

Ẹsẹ Mẹfa sọ pe iroyin ẹlẹjẹ ti wọn n gbe kaakiri igboro nipa pe oun ṣetan lati paayan lori ipo alaga toun n du naa, ko ṣẹyin awọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu Allied Peoples Movement, APM, paapaa Ismail Ọlanrewaju Yusuf to jẹ ọkan lara awọn aṣaaju wọn.

Fawọn to ba mọ bi nnkan ṣe n lọ, laipẹ yi ni igbimọ ti Gomina Dapọ Abiodun yan lati boju to bi nnkan ṣe n lọ ninu ẹgbẹ naa bawọn oloye ẹgbẹ TWORA ṣepade, lẹyin ipade naa niroyin kan jade sori ayelujara pe Gbenga Ogunwale ti sọ fawọn igbimọ naa pe ẹjẹ ọpọ awọn eeyan ni yoo ṣofo danu, tẹmi ọpọ yoo si lọ si ipo alaga naa, bi wọn ko ba fi toun ṣe lati di alaga tuntun.
Ninu ọrọ to ba AWIKONKO sọ lo ti jẹ ko di mimọ pe awọn to n gbe iroyin ẹlẹjẹ naa kaakiri fẹẹ fi ṣi igbimọ naa lọkan ati lati da nnkan ru mọ wọn loju, ati lati le fi tako afojusun oun lati di alaga ni.

O ni Yusuf Ọlanrewaju ti wọn tun n pe ni Mayasau to jẹ ọkan pataki ninu ẹgbẹ oṣelu APM toun naa n du ipo alaga yi lo wa nidi iroyin ẹlẹjẹ naa, tori pe o mọ pe oun lẹnu juu lọ.

Ẹsẹ Mẹfa fidi ẹ mulẹ pe oun ko nii ṣe ohunkohun ti yoo tako agbekalẹ ijọba, tori pe amọfin loun, toun si n tẹle gbogbo ofin orilẹ-ede Naijiria.


No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI