BI MO ṢE N DALEMOṢU N KO ITIJU BA MI PUPỌ, MI O SI ṢIṢẸ AṢẸWO O - ADAKU PARIWO SITA - IROYIN AWIKONKO

YÀJÓ-YÀJÓ
Tuesday, July 16, 2019

BI MO ṢE N DALEMOṢU N KO ITIJU BA MI PUPỌ, MI O SI ṢIṢẸ AṢẸWO O - ADAKU PARIWO SITA

Gbajumọ sọrọ ori redio nni, Ọmọtunde Adebọwale tọpọ awọn ololufẹ ẹ tun mọ si Lọọlọ ti jẹ ko di mimọ pe kii ṣe ẹbi oun pe oun n dalemoṣu, toun si tun jẹ iya n da gbe, ṣugbọn ti ko si nnkan toun fẹ ẹ ṣe sii.

Lọọlọ tawọn to tun mọ ninu gbajugbaja sinima ọlọsẹ-ọsẹ nni, iyẹn Jẹnifa tun mọ si Adaku lo sọrọ naa lasiko to n tu pẹẹrẹ-pẹẹrẹ ọrọ fun ileeṣẹ iroyin BBCYORUBA lonii nibi ifọrọwerọ ti wọn ṣe fun un.

Obinrin naa sọ pe ki i ṣe gbogbo dalemoṣu lo n ṣe aṣẹwo, bo tilẹ jẹ pe awọn kan n ṣe e, ṣugbọn iyẹn ko sọ pe koun ṣe e, tori iṣẹ toun yan laayo ko faaye gba iru iwa bẹẹ.

Ọmọ bibi ipinlẹ Ogun naa tun sọrọ lori ikọra-ẹni-silẹ, to si sọ pe ẹnu araye l'ẹbọ ninu ọrọ igbeyawo, nitori ohun ti wọn ma sọ ni pe ki lo de too ṣe sọrọ sita tabi o kuku ti n sọrọ ju.

Oṣere yii royin oun ti oju obinrin to ti kọ ọkọ silẹ n ri lawujọ Yoruba.

Bẹẹ lo sọ pe boun ṣe n dalemoṣu ti n di nnkan itiju foun, nitori pe pupọ ninu awọn ọrẹ oun lawọn ọkọ wọn ti n le lọdọ oun, pe ki wọn yẹra foun tori pe oun ko si nile ọkọ.

O ni ki i ṣe nnkan to wu oun ni boun ṣe n dalemoṣu, ati pe ko si ẹni to wu lati dalemoṣu nile aye yi.

Adaku ni awọn eeyan maa n sọ pe awọn ọmọ obinrin ti ko si nile ọkọ ko le yanju, ṣugbọn Olorun ju ẹda lọ.

No comments:

Post a CommentPÍN-IN KÁÀKIRI